IDAJỌ ỌLỌRUN

Heb 9:27 “Niwọn bi a si ti fi lelẹ fun gbogbo enia lati kú lẹ̃kanṣoṣo, ṣugbọn lẹhin eyi idajọ:”

Lati igba iwaṣẹ ni Ọlọrun ti jẹ Oludajọ fun gbogbo iṣẹ ọwọ Rẹ. A gbọdọ mọ bawo, igbawo ati idi pataki ti Ẹlẹda fi nda ẹjọ. Eyi yio jẹ atọna fun wa lati huwa tabi gbe igbesẹ ti a o fi jinna si ibinu Ẹlẹda.
“Ṣugbọn awa mo pe idajọ Ọlọrun jẹ gẹgẹbi otitọ si gbogbo awọn ti o nṣe iru ohun wọnyi” Rome 2:2. (Eniyan ko gbọdọ da enikeji rẹ lẹjọ).

“Kiyesi i, Emi mbọ kan kan, ere mi si mbẹ pẹlu mi lati san an fun olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ rẹ yoo ti ri” – Ifihan 22:12

Gbogbo ẹda ni yio gba ere iṣẹ ọwọ rẹ. Ko si ibi ti a lee sa si. ko si ojuṣaaju. Yoruba bọ, nwọn ni “O ta ọfa s’oke, o yi odo bo ori, bi Oba aiye ko ri ọ, Ọba oke nwo ọ”.

Awọn Musulumi gbagbọ wipe igbaradi fun igbe aye titun ni eyiti a wa yii. Ọjọ mbọ ti a o pa aiye yi rẹ, ti awọn oku yio ji dide fun idajọ lati ọwọ Ẹlẹda. Wọn gbagbọ wipe awọn eniyan yio gba idajọ gẹgẹbi ohun ti nwọn gbagbọ ati iṣe nwọn. Awọn ti o gba Ọlọrun gbọ ati Muhammed bi ojiṣẹ Rẹ, nikan ni nwọn gbagbọ wipe yio wọ ọrun rere (Aljana).

Ninu iwe Mimọ Bibeli, awa Kristiani ka a bi Ẹlẹda ṣe nṣe idajọ lati ibẹrẹ pẹpẹ aiye. Adamu, Efa ati ejo gba idajọ ni’gbati nwọn l’odi si ifẹ Ẹlẹda (Gen. 3 :14-19). Kaini naa fi ara gba ni’gbati o ṣe iku pa Abẹli arakunrin rẹ. Oluwa si ge egun fun un. (Genesisi 4:11-12).
Nigbati Ọlọrun Pinnu lati fi iya jẹ Sodomu ati Gomorrah fun ẹṣẹ wọn, bi o tilẹ jẹ wipe Abrahamu bẹbẹ fun aanu, sibẹ, ko si olododo mẹwa pere, ti o le mu ki Ẹlẹda yi ipinnu Rẹ pada. (Genesis 18:20-25)

Idajọ Ẹlẹda wipe; ida ko ni kuro ninu ile Dafidi, ni ‘nja l’ori awọn ọmọ Israeli titi di oni, bi o tilẹ jẹ wipe nwọn nṣẹ’gun ni ọpọ igba.

Ninu majẹmu titun (Igba keji) Ọlọrun ran Jesu Kristi wa si aiye lati wa kọ wa ni Ifẹ Ọlọrun. Lati fi ọna iye han wa. O wa, O ṣe iṣẹ Rẹ ni aṣeyege, O si pada si ọdọ Baba Rẹ. Sibẹ, ẹda kọ lati mọ riri Ọlọrun ati l’ati pa ofin Rẹ mọ.
Pupọ ninu owe ti Jesu pa ṣe afiwe idajọ Ẹlẹda, gẹgẹ bi igbesẹ fun atunṣe wa. O fihan wa bi ẹda ṣe nlo id’anu rẹ.
Fun apẹrẹ: – Talẹnti (Matt 25:14-30). Oṣiṣẹ ninu ọgba ajara (Matt. 20: 1-16). Wundia mẹwa (Matt. 25:1-13).

Iku ni ere ẹṣẹ, ati lẹhin iku, idajọ mbẹ: Gbogbo eniyan ni o ti ṣẹ, ti o si ti kuna ogo Ọlọrun. Gbogbo wa ni a ti da agbada iku, ti a o si gba idajọ. Ọpọlọpọ ẹda tilẹ maa ngba idajọ ni ode aiye, ki iku to de.

Ninu Agbo Mimọ ti igba kẹta, igbagbọ wa, bi awọn ogun ọrun ṣe fi bọ wa ni wipe; Gbogbo oku ni yio gba idajọ. Idajọ yi bẹrẹ lẹhin ogoji ọjọ ti a ba fi aiye silẹ. Ayẹwo yio wa fun akọsilẹ iṣẹ ti a gbe ile aiye ṣe. Lati mọ boya ẹmi yi peregede lati darapọ pẹlu awọn Mimọ lati maa yin Ẹlẹda ni itẹ Ogo, tabi, yio tun pada wa lati wa ṣe atunṣe awọn aṣiṣe rẹ ni aiye yi.
O niye igba ti ẹda lee pada wa fun atunṣe yi, ki o to wa gba idajọ Ẹlẹda ikẹhin ni kikun.

Ọlọrun da gbogbo ẹda enia lati sin Oun; O pe awa kan sinu Agbo Mimọ yi, O si fun gbogbo iran enia ni iṣẹ lati ṣe ki a lee ni ipa ti o j’ọju ni igbe aiye wa ni ode aiye. A nilati fi ọna ijọba Ọlọrun han awọn ẹda miran ni ode aye ninu ero, ọrọ ati iṣe wa. A ni lati wa awọn ti ko ti i ni imọ nipa ohun ti Ẹlẹda nreti lọwọ ẹda ọwọ Rẹ, ki a si fi imọ yi bọ wọn.

A ni lati fi ifẹ han si ọmọlakeji wa. A ko gbọdọ bẹru tabi tiju lati jẹki awọn eniyan mọ wipe ọmọ Agbo Mimọ ni a jẹ. A ni lati tọ awọn eniyan si ṣiṣe ifẹ Ẹlẹda.
Ọlọrun Onidajọ gbogbo ẹda ọwọ Rẹ ni o nṣe idajọ. Oun a maa ṣe idajọ ododo, O si pọ ni Aanu.
Ki Ẹlẹda, ninu aṣẹ ati oore-ọfẹ Rẹ ṣe wa yẹ, ki gbogbo wa le ri aanu gba ni ọjọ idajọ. Amin.

IRU IYAWO WO NI IWỌ?

RUTU GẸGẸ BI AWOKỌṢE. (IWE RUTU)

Rutu 1:16: “Rutu si wipe, Máṣe rọ̀ mi lati fi ọ silẹ, tabi lati pada kuro lẹhin rẹ: nitori ibiti iwọ ba lọ, li emi o lọ; ibiti iwọ ba si wọ̀, li emi o wọ̀: awọn enia rẹ ni yio ma ṣe enia mi, Ọlọrun rẹ ni yio si ma ṣe Ọlọrun mi:”.

  1. Elimeleki jẹ ara Betilẹhẹmu. Aya rẹ, (Naomi) bi ọmọ ọkunrin meji – Maloni ati kilioni, fun un. Nigbati iyan mu ni Bẹtilẹhẹmu- juda, awọn ẹbi yi ko ara wọn lọ si ile Moabu lati lọ ṣe atipo, ki wọn ba le ri onjẹ jẹ.
  2. Awọn ọmọ rẹ mejeji fẹ iyawo – Orpa ati Rutu. Awọn ara Moabu ni awọn iyawo wọnyi. Aboriṣa ni wọn. Wọn ko si bimọ.
  3. Lẹhin ọdun mẹwa, Elimeleki ati awọn ọmọ rẹ mejeeji ku. O si wa ku Naomi, Orpa ati Rutu. Asiko yii ni irohin wa wipe, iyan ti ka’sẹ ni ilẹ Bẹtilẹhẹmu.
  4. Naomi nfẹ pada si Bẹtilẹhẹmu, o si rọ awon aya ọmọ rẹ mejeji lati pada si ọdọ awọn obi wọn ki wọn ba lee fẹ ọkọ titun. Orpa gba imọran yii, o si pada si ile rẹ, ṣugbọn Rutu taku wipe oun yoo ba iya-ọkọ oun pada si ile rẹ ni Bẹtilẹhẹmu.
  5. Rutu fi ẹsin ati aṣa ati ede rẹ silẹ, o si tẹle iya-ọkọ rẹ. Ọpọ ni ọrọ ti awọn ara ilu nwi nipa Naomi ati Rutu, ṣugbọn eyi ko di Rutu lọwọ.
  6. Asiko yi jẹ igba ikore ọka baali akọkọ, lẹhin iyan – Rutu sọ fun Naomi wipe oun yio lọ si oko lati lo ṣa ẹgbọnsilẹ ọka ki wọn ba le ri onjẹ jẹ. Rutu ṣe oriire lati lọ si ọgba Boasi eniti i- se ibatan baba ọkọ rẹ ti o ti di oloogbe. Boasi wa ni oko ni akoko naa. O beere lọwọ awọn oṣiṣẹ rẹ iru ẹniti Rutu i-se.
  7. Wọn ṣe alaye fun un ni ẹkunrẹrẹ, aanu Rutu si ṣee. O gba a tọwọ-tẹsẹ o si fun un ni ẹbun ati anfaani ti o pọ. O rọ awọn oṣiṣẹ rẹ lati maṣe ni Rutu lara.
  8. Gẹgẹ bi ẹniti o mọ oore, Rutu dupe pupọ lọwọ re, “O wolẹ, o si tẹ ara rẹ ba silẹ, o si wi fun un pe, Eeṣe ti mo ri oore-ọfẹ li oju rẹ, ti iwọ o fi kiyesi mi, bẹẹni alejo ni emi” (Rutu 2:10).
  9. Boasi sure fun Rutu ni ẹsẹ ekejila wipe; ki Oluwa ki o san an li ẹsan iṣẹ rẹ.
  10. Rutu fi gbogbo ara ṣiṣẹ ninu ọgba ni ọjọ naa gẹgẹbi iṣe rẹ. Eyi jọ Boasi loju o si fun Rutu ni ọka ti o pọ. Oun ati iya ọkọ rẹ jẹ ajẹ’yo ati ajẹ’ṣẹku.
  11. Inu iya ọkọ rẹ dun o si yan lati pese ibujoko rere fun un. Naomi kọ Rutu ni ohun ti yio ṣe lati le fẹ ibatan ọkọ rẹ. Rutu gba imọran lati lọ sun si ẹba ẹsẹ Boasi. Lẹhin igbesẹ ti o tọ, o di iyawo Boasi, o si bi OBEDI – Itumọ eyi ti i-ṣe “A bi ọmọkunrin kan fun Naomi”.
  12. Rutu gbe ọmọ naa fun iya ọkọ rẹ lati tọ. O fi tu u ninu. Obedi si bi Jesse, Jesse si bi Dafidi ninu iran ẹniti a ti bi Olugbala ar’aiye – Jesu Kristi.
  13. Ẹkọ ti a kọ lara igbe aiye Rutu: –
  14. Rutu jẹ obinrin rere. O duro ti iya ọkọ rẹ pẹlu iwa ododo ninu Ọlọrun, lẹhin iku ọkọ rẹ ati ninu ipọnju.
  15. O duro gẹgẹbi aya tootọ pẹlu ibaṣepọ ninu ifẹ ati igbagbọ ninu Ọlọrunl pẹlu ẹbi ọkọ rẹ.
  16. O jẹ olododo laisi ẹtan ninu iṣesi rẹ. Rutu gbagbọ ninu Olorun Alaaye. O fi ilu ati aṣa ‘rẹ sile lati tẹle iya ọkọ rẹ.
  17. Iwa rẹ ati iṣesi rẹ mu ki alafia ati ifọkanbalẹ jọba laarin oun ati ẹbi ọkọ rẹ.

ẹ. Rutu jẹ akikanju obinrin. O ṣe iṣẹ tọkan–tara ni oko Boasi lati toju iya ọkọ rẹ.

  1. Rutu jẹ iyawo olotitọ ati obinrin rere ti o duro dede, lẹhin iku ọkọ rẹ, bi o tilẹ jẹ wipe ko bimọ, o gbọnran si iya ọkọ rẹ lẹnu eyi si mu ki igbe aiye rẹ yipada si rere.
  2. Rutu fi ara balẹ titi Boasi fi ṣe ohun ti o tọ ninu ẹbi wọn lati maṣe mu itiju ba ara rẹ.
  3. Ọlọrun san ere iṣẹ rere rẹ fun un nipa fifun-un ni olu-ọmọ nipasẹ ẹniti Olugbala fi wa si aye.
  4. Mo rọ awa ọmọ Agbo Maria Mimọ ati gbogbo iyawo-ile lapapọ, lati kọ ẹkọ ninu igbe aiye Rutu ki ile wa ba le jẹ ile alayọ. Ọpọ ni awọn obirin ti ko le fi ara da, iya ati baba ọkọ wọn. Ti ẹbi ọkọ ko jẹ ohunkohun fun nwon. Li otitọ; ile ọkọ, ile ẹkọ ni, ṣugbọn, bi a ba fi ara b’alẹ, ti a si ni amum’ọra, ohun gbogbo yio tuba-tuṣẹ. Suru igba diẹ, a maa fun obinrin ni anfani pupọ lati jẹ ere ile ọkọ ni ẹkunrẹrẹ.

AGBARA AHỌN, LATI KỌ TABI BIWO

Ẹyin Ayanfẹ Ilẹ Miṣẹni ati ẹyin ti a k’ọju si ṣe l’oore, ti a si yan, ti o tun ni anfani, lati jẹ ẹlẹri si, igba ati fifi Ọba titun Rẹ si ori oye, gẹgẹbi aṣooju BABA ni aarin awọn eniyan Rẹ; maṣe gba ki igbera-ẹni-ga, oju kokoro, ilara, ibinu oun ikorira, jẹ atọkun aiye rẹ, gẹgẹbi ọmọ Ilẹ Miṣẹni.

Gẹgẹbi ẹlẹran ara, o di dandan ki akoko ibinu ati ede-aiye’de wa laarin awa ọmọ enia; ṣugbọn, ni akoko bi eyi; a ko gbọdọ sọ ọrọ buburu tabi ọrọ aidara ni akoko ibinu.
Nitori, ibinu ọkan yio lọ’le lẹhin igba diẹ, ṣugbọn, ki yio si anfani lati gba pada, ọrọ ti iwọ ti sọ s’ilẹ.
A ni lati maa lo ọgbọn pẹlu iṣọra fun awọn ọrọ ti yio ma ti ẹnu wa ja de.

Ahọn jẹ ohun elo fun aṣẹ.
Bi o tilẹ jẹ wipe ọpọ enian ni wọn nlo ahọn, diẹ ninu nwọn ni o mọ ipa ati wiwuwo rẹ.
Eeṣe ti awọn ẹranko ko lee sọrọ?
Awọn eweko ati oke nla pẹlu?
Bawo ni ọmọ enian ṣe wa ni anfani lati maa sọ ọrọ?
Idi ni wipe, a da ọmọ enian ni aworan Ẹlẹda ni ẹkunrẹrẹ, ni ọna ti awọn ohun iṣẹ ọwọ Rẹ gbogbo ti o ku ko ni anfani bayi.

Ti Ẹlẹda ba ti paṣẹ, o ti di ṣiṣe.
Eyi ni agabara ti enian ni, ṣugbọn ti oye rẹ ko ye ọpọ ninu wa. A si ma nro wipe, ti a ko ba ri ipa ọrọ ti a sọ ni kiakia, pe iru ọrọ bẹẹ, ko ja mọ nkankan ni.
Ere aini igbagbọ ni eyi. Gẹgẹbi ọjọgbọn ti o fẹ esi ni kia kia, mọ daju wipe, ti iwọ ba ti pe gbolohun ifẹ ọkan rẹ, lọgan ni imuṣẹ rẹ ti bẹrẹ.

Ọrọ ni itumọ. Bi iwo ba si ṣe tumọ ọrọ, bẹẹ ni agbara ọrọ bẹẹ yio ṣe dari iwọ ati ayika rẹ.
Ọrọ ti iwọ ba sọ pẹlu igbagbọ yio ri imuse pipe, bakanna ni eyi ti nṣe ọrọ awada. Ọrọ ẹfẹ, eyi paapa ni agbara aṣẹ tirẹ.
Aṣẹ ọrọ, lati inu wa ni eyi, oun yio si d’arapọ mọ agbara ti ode. Itumọ eyi ni wipe, ọrọ ti a bi fi igbagbọ pipe sọ, eyi yio wa iru ara rẹ kaakiri agbaiye, imuṣẹ ọrọ bẹẹ ni ẹkun rẹrẹ yio si ṣẹlẹ.

Ti ọrọ ba ti jẹ sisọ, ero ọkan rẹ ni eyi. Eyi ni ohun ti awọn Woli iṣaju sọ wipe; ‘‘ọrọ ẹnu rẹ, ki yio pada, lai ṣe iṣẹ, eyi ti iwọ ran an’’. Sibẹ, ọpọ a si sọrọ ti ko ni anfani kan pato.
Nitori naa, gbiyanju lati s’ọrọ pẹlu ero ọkan pipe ni igba gbogbo, bẹẹ ni, iwọ yio si ri agbara ti iwọ ni.

Ninu oyun abiyamọ, lẹhin oṣupa mẹsan ni ọmọ titun yio jẹ bibi si inu aiye. Oye fi ye wa wipe, ọmọ titun yi ti wa ni aaye ni gbogbo akoko yi, nitori wipe, ẹmi mbẹ ni gbogbo igba.
‘ẸMI’ ti wa, ki oyun to de.
Ọrọ, ẹmi ni.
Bayi ni ki iwọ ri ahọn rẹ, gẹgẹbi ohun elo ti o ngbin eso. Ero ọkan rẹ ni yio si sọ iru eso ti yio jẹ gbigbin. Idagba-soke eso bẹẹ pẹlu, yio rọ mọ ero ọkan rẹ, iṣesi ati ọrọ ẹnu rẹ.
Ti iwọ ba gbin eso rere, ti iwọ si bu omi rin, baa sọrọ ni gbogbo igba pe, ki o so eso rere, yio si ni ikore rere.

Ti iwọ ba gbin eso rere, ṣugbọn ti o ko b’ojuto, lotitọ yio hu jade, ṣugbọn, ikore rẹ ko le dabi.
Ti iwọ ba gbin eso buburu ti eyi si ṣe ako’ba fun ohun ọgbin rẹ ti o ku, ara rẹ ni iwọ yio da lẹbi.

Eyi ni ohun ti Angẹli Rafaẹli sọ nipa ahọn:
Lo ahọn rẹ fun iyin Rẹ, ati ohun gbogbo ti o wa fun gbigbe orukọ Mimọ Rẹ ga nikan.
Lo ahọn rẹ fun mimu ireti ati ayọ ba eti ti o gbọ ọ.
Lo ahọn rẹ fun mimu o sunmọ Ijoko Rẹ, yio si dara fun ọ.
Ahọn kii da ṣe iṣẹ. Ifihan ahọn rẹ ni ọrọ ti iwọ ba sọ. Bẹẹ ni, lati inu ero ọkan rẹ ni ọrọ ti iwọ sọ jade ti suyọ. Dajudaju, ọkan rẹ ni atọkun fun ahọn rẹ. Eyi ni yio si dari ọrọ ti iwọ ba sọ, ati bi iwọ yio ṣe sọ ọ pẹlu.
Nitori idi eyi, ṣe akoso ọkan rẹ ni daradara, ki o si mọ agbara ti mbẹ ninu ahọn rẹ.

Ọlọgbọn yio sọ wipe, ninu eko iṣiro; ohun meji pẹlu ohun meji, eyi yio di ohun mẹrin. Otitọ ni oun sọ.
Alaimọkan a si ṣe iṣiro wipe; idapọ ohun ọkan pẹlu ohun ọkan, yio di ohun mẹta. Ṣugbon ahọn tirẹ ko sọ otitọ, bẹẹ ni ko sọ bi o ṣe ri. Iparun ni eyi.
Otito a maa kọ ile, irọ a si maa bi i wo. Nitori idi eyi, gbiyanju ki otitọ maa fi ara han ọ, tobẹẹ, ti iwọ ba sọrọ, iwọ yio maa kọ ile ni, dipo bibi i wo.

Kini eyi tumọ si?
O tumo si wipe, Ahọn (ọrọ) ni agbara kikọ tabi bibajẹ, ṣugbọn orisun agbara bi eyi, ni ọkan (ero), iṣesi ati idawọle rẹ.

Lati gberu, ẹda ni lati ṣe aṣaro lori otitọ, fi agbara ninu otitọ han, ki oun si gbe igbe aiye otitọ. Ẹni ti o ba ṣe eyi, oun yio maa gberu si ninu aaye rẹ, ati ni ayika rẹ pẹlu. Nitori wipe, ti ẹda ba gbọ otitọ, eyi da bi eso rere ti o jẹ gbingbin si ọkan rẹ, eyi ti o si ni anfani lati so eso rere.

Ni idakeji ẹwẹ, ibajẹ yio jẹ ti ahọn ti o kun fun irọ pipa, ati aiṣe ododo. Eyi yio si mu idaamu ati irukerudo wa, eyi ti yio si ṣe okunfa iparun fun ẹda bẹẹ, ati awọn ti o yi ẹda bẹẹ ka.
Nitori idi bi eyi, ẹda ni lati ṣọra nipa ero ọkan, ati isọrọ ẹnu jade.
Beere lọwọ ara rẹ, njẹ ti iwọ ba sọ ero ọkan rẹ jade, njẹ iwọ nṣe ikọle (otitọ sisọ) ni, tabi, iwọ nṣe ibajẹ (titan irọ ka)?
O dara ki o pa ẹnu rẹ mọ ju wipe, ki o ṣe okunfa irukerudo ati ibajẹ lọ.
Ẹyin arami….
Ẹ ṣọ ero ọkan nyin;
Ẹ ṣọ ọrọ ẹnu nyin;
Ẹ ṣọ iṣesi nyin.

Ẹ ṣọra fun ipolongo idajọ irọ. Ọlọrun nikan ni O wa ni ipo Idajọ otitọ. Gba ẹda gbogbo bi won ṣe jẹ, ki o si yẹra fun idalẹbi nwọn lai fi idi ododo mulẹ. Eyi paapa jẹ ọna ibajẹ fun iwọ ati eti ti o gbọ ọrọ bẹẹ.

Tiraka lati gba ẹda gbogbo gẹgẹbi aworan Ẹlẹda. Kọ oju si iṣe ati idagbasoke tirẹ, eyi ni iṣẹ naa, ti a pin fun ọ.
Ti iwọ ba ni akoko to bẹẹ lati polongo idajọ fun arakunrin rẹ, yala ni didara tabi ni buburu, eyi fi han wipe, ohun ti ko ni anfani, ni iwọ nfi ngba ọkan rẹ ni’ṣe. Eyi si npe fun atunṣe.

Aworan ati iriri Ọlọrun, ki i ṣe ohun ti a nf’ojuri. Ṣugbọn eyi ni agbara lati dabi Ọlọrun.
Ọlọrun ko dabi iriri ọmọ enian, ti a nwo. Itumọ eyi ni wipe ninu ọmọ enian ni ohun gbogbo ti o duro fun Ọlọrun gbe wa.

Ọlọrun, A maa ronu,
Ọlọrun, A maa sọrọ,
Ọlọrun, A maa ṣiṣẹ.

Ti iwọ ba mọ eyi, ti o si nṣe imulo ero ọkan rẹ ni akoko, igbayi ni iwọ yio da bi Ọlọrun. Ṣugbọn, ọpọ ni o ti padanu iru ipo bi eyi, nitori ohun ti aiye.

Ohun ti Ọlọrun, ti aiyeraiye ni.
Iwọnyi si nji dide lati ipo oku.
Iwọnyi a si maa sọ di alaaye.

Ohun aiye yio di ibajẹ, iwulo nwon yio si ba aiye lọ.
Ahọn ni agbara pupo nitori ipo aṣẹ ti o wa. Ohun ti ahọn ba si sọ, eyi jade wa lati inu ero ọkan ẹda ni.
Idi ni eyi ti o fi jẹ wipe, agbara Ahọn le mu ilosiwaju wa, o si le ba nkan jẹ pẹlu.
Gba lati maa kọ ipilẹ rere ni igba gbogbo.

OORE – ỌFẸ ATI OFIN ỌLỌRUN

Oore-ọfẹ! Ohun
Adun ni l’eti wa;
Gbo’un-gbo’un rẹ y’o gba ọrun kan,
Aiye y’o gbọ pẹlu.
Oore-ọfẹ ṣa
N’igbẹkẹle mi;
Jesu ku fun araiye,
O ku fun mi pẹlu.

Awọn kristiani maa nlo ọrọ yi – (oore-ọfe) laibikita, nitori nwọn ro wipe awọn ti mọ ohungbogbo ti nwọn ni lati mọ nipa oore-ọfẹ. Oore-ọfẹ jẹ ohun oju rere ti ko tọ si wa lati ọdọ Ọlọrun. Lootọ ati ni ododo, ṣe oju rere ti ko tọ si wa ni oore-ọfẹ jẹ?

Aposteli Paulu ninu iwe rẹ si awọn ara Romu, ori ikarun ẹsẹ ogun (Romans 5:20) kọ wa pe “nibiti ẹṣẹ ba ti npọ sii, oore-ọfẹ a maa pọ sii pẹlu.” Ṣugbọn oun yara lati sọ pe eyi ki nṣe iwunni lori lati maa gbe igbe aiye aibikita – kini ki ati wi nigba naa? Ṣe ki a maa gbe ninu ẹṣẹ ki oore-ọfẹ le maa pọ sii bi? Ki eyi ki o maa ṣe ri bẹẹ rara.
Eeṣe ti awa ti a ti ku si ẹṣẹ, maa gbe ninu rẹ bi (ẹṣẹ)? Iwe Romu ori ikẹfa ẹsẹ ikini si ekeji (Romans 6:1-2) beere lọwọ wa – “kinni oore-ọfẹ Ọlọrun ati pe kinni eyi jẹ si wa? Ni titumọ oore-ọfẹ Ọlọrun, ngo gbiyanju lati lo awọn ohun ti onkọwe kan ti kọ silẹ.

Oore jẹ ekinni iwa ti o rọ mọ Ọlọrun ti o si njẹ iwa ara ọmọ enia. Idajọ Ọlọrun; Iwa Mimọ Ọlọrun; Ọlọrun ti agbara Rẹ wa ni ibi gbogbo; ti imọlẹ ijinlẹ Rẹ si kari aiye; gbogbo iwọnyi jẹ iwa àmọ̀mọ́ ni Ọlọrun, ṣugbọn oore-ọfẹ duro gedegbe, ti oun si jẹ apakan iwa Ọlọrun ti o farahan ninu majẹmu lailai.
Awọn ọmọ Ọlọrun bi Dafidi nwo Ọlọrun bi Oloore-ọfẹ. Iwe orin Psalm ori kẹta-le-lọgọrun (Psalm:103), kun fun iyin ati idupẹ, eyi ti o nfi oore-ọfẹ Ọlọrun han.

Ohun ti o fi han gbangba oore-ọfẹ Ọlọrun ni wiwa si aiye Jesu Kristi, ti Oun si ku fun awa ẹlẹṣẹ, ti a si de ni ade iṣelogo, Heberu Ori ikeji ẹsẹ ikẹsan. Igbala wa jẹ pipọ ninu ọla oore-ọfẹ Rẹ -Efesu Ori ikinni, ẹsẹ ikeje. Ipe wa ninu ominira Ẹlẹda jẹ eyiti ko ṣe iyipada ninu oore-ọfẹ Rẹ, Iwe Galatia Ori ikinni ẹsẹ ikarundinlogun. Idalare, eyi ti o ti inu idajọ wa wipe, awa jẹ ẹni idalare kuro ninu ẹbi ninu i-ṣe Jesu Kristi, eyi jẹ ẹbun oore-ọfẹ. Iwe Romu Ori kẹta ẹsẹ ikẹrinlelogun, ati iwe Titu Ori ikẹta, ẹsẹ ikeje (Titus 3:7).
Ninu apapọ ọrọ Rẹ, gbogbo ẹka iṣẹ igbala ni o jẹ iṣẹ Ẹlẹda (Ọlọrun) fun oore-ọfẹ, eyi ti ki i ṣe iṣẹ ọwọ wa.


Oore-ọfẹ lo kọ
Orukọ mi l’ọrun
Lo fi mi fun Ọd’agutan
To gba iya mi jẹ.

Bi o tilẹ jẹ pe akori Oore-ọfẹ Ọlọrun ni agbelebu oke Kalfari, a le ṣe apejuwe oore-ọfẹ ni oriṣiriṣi ọna.

i) Oore-ọfẹ ti o wọpọ – Eyi ni oore-ọfẹ ti Oun fun gbogbo enia – nitori Oun
mu ki oorun ran sori ẹni ibi ati ẹni ika ati ẹni ire. Oun si nrọ ojo si ori
olododo ati alaiṣododo. Matiu Ori ikarun ẹsẹ ikẹrinlelogoji si ikarundin-ni-
aadọfa. Ọlọrun kun fun oore-ọfẹ lati mu igbala wa fun gbogbo enia nipa sisun idajọ Rẹ siwaju, nipa eyi ti Oun fun wa ni okùn ti ogun fun ironupiwada. –Peteru keji, ori kẹta ẹsẹ ikẹsan.

ii) Oore-ọfẹ igbala –Iṣe Awọn Aposteli Ori ikarundinlogun, ẹsẹ ikọkanla, eyi ti iṣe oore-ọfẹ aabo lori igi agblebu.

iii) Oore-ọfẹ iwẹnumọ – eyi ni oore-ọfẹ ti nṣiṣẹ ninu onigbagbọ ododo lati mu idagba soke, itẹsiwaju ati gbigbọn ninu fifi iwa jọ Kristi.
Inu didun ni awọn ti wọn bẹru lati ya kuro loọna idajọ Rẹ ti nwọn mọ ti nwọn si fẹran ọna Rẹ ti nwọn si npa ododo ati ofin Rẹ mọ, ti nwọn si nṣe wọn.

iv) Oore-ọfẹ iṣẹ, ni oore-ọfẹ ti o gba ọ laaye lati lo ibukun ti ẹmi fun ogo Ọlọrun ati fun ire ati anfaani ọmọ enia.
v) Oore-ọfẹ imuduro – Oore-ọfẹ yi fun enia ni pataki ni imuduro ni akoko wahala ati ijiya.
Oore-ọfẹ nwa wa ri, o ngba wa la, pa wa mọ, dabobo wa, o nsun wa siwaju o si ngba wa laaye lati sin ati lati farada idanwo ati wahala aiye. Irin ajo aiye wa jẹ iranlọwọ at’oke wa. Eyi mu wa wa si ọrọ ai-yẹ tabi iyemeji tabi aini igbagbọ aaye wipe oore-ọfẹ ngbè wa, nitorina a le wa lailo ofin.

AWỌN OFIN ATI OORE-ỌFẸ ỌLỌRUN
Ṣe ki a wipe awọn baba wa ati awọn ẹni igbagbọ igbaani ngbe ninu igbagbọ pe oore-ọfẹ ti o bo ẹṣẹ mọlẹ ati pe ofin ko lagbara kan lori awọn mọ? Ibaṣepọ oore-ọfẹ ati ofin jẹ ọkan ninu awọn ohun ti o nfa rudurudu silẹ laarin awọn onigbagbọ. Awọn onigbagbọ kan gba ara wọn wipe a ko wa labẹ ofin tabi aṣẹ kan nitorina a le gbe igbe aiye bi a ti fẹ. Ṣugbọn Paulu Aposteli ninu iwe rẹ ikinni si awọn ara Kọrinti Ori ikẹẹdogun ẹsẹ ikẹwa: “Ṣugbọn nipa oore-ọfẹ Ọlọrun, mo ri bi mo ti ri, oore-ọfẹ Rẹ ti a fi fun mi, ko si jẹ asan; ṣugbọn mo ṣiṣẹ lọpọlọpọ ju gbogbo wọṅ lọ; ṣugbọn ki i ṣe emi bikoṣẹ oore-ọfẹ Ọlọrun ti o wa pẹlu mi”.
Aposteli Paulu wi nihin pe oore-ọfẹ ko wa laisi ojuṣe ati pe oore-ọfẹ wa fun awọn ayanfẹ Rẹ nipa aniyan, igbiyanju, ero ati i-ṣe wọn. Oore-ọfẹ Ọlọrun to fun awọn tiRẹ ati pe iwọn rẹ a maa kun oju oṣuwọn. Raphael, Anael, Gabriel

Paulu, gẹgẹbi olupolongo oore-ọfẹ Ọlọrun ninu iwe rẹ si awọn ara Romu Ori ikẹta, ẹsẹ ikọkanlelogun si ọkanlelọgbọn ṣe ipari ni ẹsẹ ikọkanlelọgbọn pe: “AWA HA NSỌ OFIN DASAN NIPA IGBAGBỌ BI? KI A MA RI, ṢUGBỌN A NFI OFIN MULẸ.” Oun tẹ siwaju lati sọ ni iwe Romu Ori ikẹfa, ẹsẹ ikinni si ikeji pe “ Njẹ awa o ha ti wi? Ki awa ki o ha joko ninu ẹṣẹ, ki oore-ọfẹ maa pọ sii?

Ninu iwe Romu Ori ikẹfa ẹsẹ ikarundinlogun si ikejidinlogun Paulu tẹsiwaju lati beere pe –“Njẹ kinni? Ki awa ki o ha maa dẹṣẹ, nitoriti awa ko si labẹ ofin, bikoṣe labẹ oore-ọfẹ? ki a ma rii.” Oun polongo nihin nipa aidọgba pe oore-ọfẹ ha mu ojuṣe wa kuro lat bọwọ fun ofin Ọlorun bi?

Ẹkọ mi nipa oore-ọfẹ Ọlọrun kuru pupọ, ṣugbọn eyi ran mi leti nipa aanu Ẹlẹda si awa enia Rẹ. O yẹ ki a mọ pe didara ni ohun gbogbo ti o ba ṣẹlẹ si awa ọmọ enia, ati pe lati ọdọ Ọlọrun Oloore-ọfẹ ni eyi ti wa. O si tun han si mi wipe awọn enia ko bẹru Ọlọrun, nwọn a maa mu Ọlọrun pẹlu aibikita. Wọn tumọ oore-ọfẹ Rẹ gẹgẹbi Ẹni alailagbara ati ifasẹhin idajọ Rẹ gẹgẹbi Ẹniti ko ni idi Pataki lati mu Ileri Rẹ ṣẹ. Awa ọmọ enia ti o npafọ ninu ọna aidọgba ati ẹṣẹ gbogbo, ko ṣe tan lati gba idalẹbi ara wa rara nitori ẹtanjẹ eṣu, nitori ori kunkun ko jẹ ki wọn mọ ọna ati bẹbẹ fun oore-ọfẹ Ọlọrun. Ọlọrun alaanu ni Oun, ti awa ẹlẹṣẹ ba le jẹwọ ẹṣẹ wa, ki a si pe fun igbala kuro ninu ẹṣẹ wa. Oore-ọfẹ Rẹ wa fun emi ati iwọ gẹgẹbi ẹlẹṣẹ. Ewo li o pe wa julọ, ninu ki Oun fi Oore-ọfẹ Rẹ gbọ tiwa tabi ki a kuku gba ere ẹṣẹ wa lẹkun rẹrẹ ninu aiko gba oore-ọfẹ igbala ti Oun fi fun wa?

Ki oore-ọfẹ Ọlọrun to fun wa ninu iwulo rẹ fun wa, ati pe ki awọn enia ri oore-ọfẹ yi ninu wa fun iyin ogo orukọ mimọ Rẹ. Amin.

Jẹki Oore-ọfẹ yi
F’agbara f’n ọkan mi
Ki nle fi gbogbo ipa mi
A t’ọjọ mi fun Ọ.
Oore-ọfẹ ṣa ni igbẹkẹle mi
Jesu ku fun araiye
O ku fun mi pẹlu. Amin.

Read more

IJỌBA ỌLỌRUN – IHINRERE KRISTI SI ENIA GBOGBO

1. Ẹkọ Bibeli fun ọrọ iṣiti oni ni a mu lati Ihinrere Luku 8:1-3, eyi ti o ka wipe:
“O si ṣe lẹhinna, ti o nlà gbogbo ilu ati iletò lọ, o nwasu, o nrò ìhin ayọ̀ ijọba Ọlọrun: awọn mejila si mbẹ lọdọ rẹ̀.
Ati awọn obinrin kan, ti a ti mu larada kuro lọwọ awọn ẹmi buburu, ati ninu ailera wọn, Maria ti a npè ni Magdalene, lara ẹniti ẹmi èṣu meje ti jade kuro,
Ati Joanna aya Kusa ti iṣe iriju Herodu, ati Susanna, ati awọn pipọ miran, ti nwọn nṣe iranṣẹ fun u ninu ohun ini wọn.”

2. Jesu ninu ihinrere rẹ lati polongo ijọba Ọlọrun gba awọn ọkunrin ati obirin laaye lati ni ipin ninu itanka ijọba Ọlọrun yi, laisi iyasọtọ, idalẹbi ati itanu awọn ti o ku diẹ kaito fun ati paapa awọn ti awa ọmọ enia ti gbagbọ wipe o ti sọnu.

3. KINI IJỌBA TITUN ỌLỌRUN YI GAN?
Jesu ninu ẹkọ rẹ nipa ijaya ati aniyan ọmọ enia ni Mat 6:33 sọ wipe:
“Ṣugbọn ẹ tète mã wá ijọba Ọlọrun na, ati ododo rẹ̀; gbogbo nkan wọnyi li a o si fi kún u fun nyin.”

4. Ijọba titun Ọlọrun ni koko ọrọ iyanju ti Jesu Kristi fi bọ gbogbo enia ni orilẹ ede aiye. Eyi ki iṣe ohun ti a nwa kiri, ṣugbọn ohun ti ngbe inu wa gẹgẹbi Ẹmi Ọlọrun fun gbogbo ẹniti o gba Jusu gbọ gẹgẹbi Ọmọ Ọlọrun ati Olugbala araiye.
Eyi si jẹ ohun ti awa ọmọ enia ti nlepa rẹ lati igba ati akoko Jesu Kristi, Oluwa wa titi di oni yi.

5. Luku 17:20-21: “Nigbati awọn Farisi bi i pe, nigbawo ni ijọba Ọlọrun yio de, o da wọn li ohùn pe, Ijọba Ọlọrun ki iwá pẹlu àmi:
Bẹ̃ni nwọn kì yio wipe, Kiyesi i nihin! tabi kiyesi i lọhun! sawõ, ijọba Ọlọrun mbẹ ninu nyin.”

6. Ni ifesi si awọn Farisi, Jesu Kristi fi ye gbogbo enia wipe ijọba Ọlọrun yi ngbe inu ọmọ enia gẹgẹbi ẹmi Ọlọrun. Bi a si ti ngba Jesu Kristi sinu aiye wa, ijọba yi yio ma gberu, fidimulẹ ati gbooro si i ni ọkan onigbagbọ.
Ilàkaka lati wọ̀ oju-ọ̀na tõro, ṣe pataki, nitori ọpọ enia ni yio wá ọ̀na ati wọ̀ ọ, ṣugbọn ti nwọn kì yio le wọle. Eyi pe fun igbiyanju lati tẹle ẹkọ ti Jesu Kristi kọ awa onigbagbọ.

7. Ni ode oni ọpọ ni ile ijọsin, ọpọ ni awọn ojiṣẹ Ọlọrun, ọpọ ni ikede ati iwasu ọrọ Ọlọrun, bẹẹ ni ọpọ ni i-ṣe adura ti o ngberu si i lati ọwọ awa onigbagbọ. Sibẹ ọpọ ọmọ enia ṣi wa ninu igbekun ẹṣẹ, bẹẹ ni iṣoro, ipọnju ati ijakulẹ ni igbesi aiye ọpọ onigbagbọ npeleke si i, laisi iyipada tabi idande. E ṣe?

8. Ohun ti o fa ipo ijakulẹ bayi ni aiye awa onigbagbọ ni wipe, a kọ lati kẹkọ ninu iriri wa ti atẹhinwa. Adamu ati aya rẹ Efa kọsẹ nipasẹ ayika wọn. Eṣu lo ohun ti o wa ni ayika wọn lati ba agbara ti Ẹlẹda da mọ wọn ninu jẹ. Iru ọna madaru bayi ni eṣu yi nfi gbọn ire ọpọ ọmọ enia ati ni pataki awa onigbagbọ danu titi di oni yi.

9. Awa onigbagbọ, ani awa ọmọ lẹhin Kristi ti ode oni fẹ ohun aiye yi ju ti ohun ẹmi lọ. Dipo ki a maa dagba soke ninu agbara ti ẹmi, ti nṣe ohun ti Ọlọrun fi ṣẹda ọmọ enia ni dida a ni iriri ati aworan ara Rẹ, ṣe ni awa ọmọ enia nle owo, ọla, ipo, ohun afẹ aiye, papa julọ ni ile ijọsin, ani ni ile Ọlọrun.

10. Idiriji ẹṣẹ, ironupiwada, ibẹru Ọlọrun, iye ainipẹkun, iwa mimọ, ifarada, ọrun apadi gbogbo iwọnyi ti di ohun igbagbe ninu ijọ Ọlọrun. Oluṣọ aguntan ti di iranṣẹ eṣu, ẹniti ohun aiye ati ifẹ ẹran ara ti bo loju. Ile Ọlọrun ti di ibi owo, ni bi ti ọrọ Ọlọrun ko ni ipa mọ. Ọpọ ile ijọsin ni a da silẹ lati ko ọrọ jọ, lati ọwọ awọn aiyederu alufa. Ọpọ ijọ ni ki iṣe ijọ Kristi, ti iṣe ijọ ọmọ enia lasan.

11. Mat 16:26 “Nitoripe ère kini fun enia, bi o jèrè gbogbo aiye, ti o si sọ ẹmí rẹ̀ nù? tabi kili enia iba fi ṣe paṣiparọ ẹmí rẹ̀?”
Ole ti ara ni ọpọ awa onigbagbọ nlo igba ati akoko wa lati ba jijakadi, nigbati a fi ẹmi ati ọkan wa silẹ lai daabobo fun eṣu lati gbakoso rẹ. Ọpọ ni aṣiro ati aṣiṣe awa ọmọ lẹhin Kristi, wipe pẹlu iku Jesu Kristi oore-ọfẹ wa lati jogun idariji ẹṣẹ, nigbati ko si ironupiwada. Irọ nla li eyi. Ko si ore-ọfẹ kan ti ko ni ipa ti ọmọ enia ni lati ko, ki o to le jogun eyi. Laisi ironupiwada ko lee si isọji ati isọdọtun fun ijọ Ọlọrun ati awọn olusin.

12. Ẹ jẹ ki a wa ni idide duro lati kọ orin ipinnu wa.
We have a gospel to proclaim
Good new for all throughout the earth
A gospel of our Father’s love
We sing His glory tell His worth.

We will not fear or be dismayed
By those who sneer or laugh at us
We have the confidence to say
That we shall forge ahead with faith.

Help us dear Lord, to trust in Thee
To do Thy will and never faint
Help us to hold our heads high up
And face the task on us bestowed. Amen.

13. Kọ wa Oluwa ki awa ki o le maa ka ọjọ aiye wa, ki a le maa fi ọkan wa si ipa ọgbọn. Amin.
Njẹ nisisiyi si Ọlọrun Baba, Ọmọ ati Ẹmi Mimọ ni a fi ọla, ogo, ipa, agbara, ijuba, ọpẹ, ibukun ati iyin fun, kai ati lai lai. Amin.

I-ṢE AWỌN AKỌNI AKIKANJU

Ninu idije idibo fun ipo Arẹ orilẹ edẹ Amẹrika, eyiti o waiye ni ọdun diẹ sẹhin; ni a ti ri Akọni kan, ninu idije du ipo Arẹ ni orilẹ ede naa, lara awọn oludije fun ipo nla agbanla aiye yi.

Obirin bi ọkunrin yi, ti orukọ apejẹ rẹ njẹ Hilari Klintin, ni oludije ọkunrin akin-ẹlẹgbẹ rẹ ṣe apejuwe rẹ bayi gẹgẹbi akikanju ẹniti o ni igboya, ipinnu, aṣeyọri ati aṣeyege: laisi ibẹru tabi ifoya kan ti o tako ipinnu rẹ wipe – oun yio gbe igba oroke dandan lati di Arẹ orilẹ ede Amẹrika.

Ninu ọrọ tirẹ, Akọni Akikanju Olujide ati arabinrin yi – Hilari Klintin fi ẹnu ara rẹ sọ bayi “Emi funra tikalara mi mọ wipe, mo ti ṣetan, mo si ti pinnu lati jẹ obinrin akọkọ ti yio di Arẹ orilẹ ede Amẹrika lai wo ariwo ọjọ ati lai nani irohin ibajẹ awọn akọrohin ati akojọpọ awọn irohin iwọsi bẹẹ lori erọ aiyelujara, eyiti ki yio tu irun kan lara mi lori ipinnu ọkan mi lati gun ori aleefa gẹgẹbi Arẹ ati aṣiwaju orilẹ ede Amẹrika.”

Ẹnyin ara mi ninu Oluwa, njẹ mo bere lọwọ nyin, kini yio jẹ ipinnu emi ati iwọ nigbati ipenija ba de lori iṣẹ iriju eyiti Oluwa fi ran wa si iran enia? Ẹ jẹ ka ronu!

Eyi mumi ranri itan igbesi aiye iranṣẹbinrin kan ninu Iwe Mimọ ti a mọ orukọ apejẹ rẹ si Debora (Iwe Onidajọ, ori kẹrin ati ẹkarun). Itan igbesi aiye ati iṣẹ iriju arabinrin yi, ni mo woye wipe, o yẹ ki o jẹ ipenija nla fun iwọ ati emi gẹgẹbi obiirin lawujọ awọn ọkunrin ni saa igbe aiye ti akoko wa yi.

Akọsilẹ Akọni Akin-Obinrin yi fi ye wa wipe, ṣiṣe ifẹ Ẹlẹda ati jijẹ ohun elo iyebiye lọwọ Ọlọrun ko pin si ọdọ awọn ọkunrin nikan. Ọlọrun ninu eto mimọ Rẹ A maa lo awọn obinrin gẹgẹbi ohun elo iyebiye lati maa ṣe ifẹ Rẹ ati lati mu ipinnu ati aṣẹ Rẹ ṣẹ fun awọn ayanfẹ ati enia ini Rẹ.

Gẹgẹbi Debora ti jẹ ohun elo rere lọwọ Ọlọrun lati fi igboya ati ọkan-akin fun awọn ọmọkunrin Isirẹli pẹlu asọtẹlẹ iṣẹgun ti Ọlọrun ti pese silẹ fun wọn, bẹẹ gẹgẹ ni iwọ ati emi bi obinrin, jẹ ohun-elo iyebiye lọwọ Ọlọrun, bi a ba ti ṣetan, ti a si ti pinnu lati jọwọ ara wa silẹ fun ilo Rẹ.

Debora, Akọni Akin-Obirin ninu Iwe Mimọ jọwọ ara rẹ fun ilo Ọlọrun. Oun Ọlọrun si fi Sisẹra – ọta Isirẹli lee lọwọ ki iṣẹgun aṣẹtan lee jẹ ti awọn enia Rẹ.

Ẹnyin ara ninu Oluwa, ipenija nla ni itan yi jẹ fun gbogbo obinrin ọmọ lẹhin Kristi, gẹgẹbi oluranlọwọ Ade-Ori wa ni igbe aiye wa yi.
Ki a ma ṣe ri ẹniti yio dagunla tabi ka’wọrọ laiṣe ojuṣe rẹ ninu ọgba ajara Rẹ yi.
Agbara mbẹ fun awa obinrin yalla lati tunṣe tabi ṣe idakeji rẹ.

Mo bere, irufẹ obinrin wo ni iwọ ati emi ninu ijọ Ọlọrun ati lọdẹdẹ ọkọ wa?

Hilari Klintin gẹgẹbi Debora ninu Iwe Mimọ jẹ apẹrẹ rere awọn Akọni, Akikanju Akin-Obinrin ti ko gbadọ ninu aṣa na wipe, iyara-ibusun ati ẹhinkule ni ile-idana ni ipo awọn obinrin wa. Ṣugbọn yatọ si ero bẹẹ, awọn arabirin wọnyi ji giri si lilo ẹbun ati ore-ọfẹ ti Ọlọrun fi fun wọn – eyiti i-ṣe ẹmi akin, igboya, ọgbọn, imọ, oye ati ti akọni-loju-ija fun iṣẹ Rẹ lai wipe ohun kan wa ti wọn ko le dawọle gẹgẹbi awọn ọkunrin Akin-ẹlẹgbẹ wọn. Igbagbọ awọn Akọni Akin-Obinrin wọnyi ni wipe, ohun ti ọkunrin le ṣe obinrin le ṣe daradara ju bẹẹ lọ.

Ohun kan ni, Obinrin bẹẹ ni lati ni igbagbọ ati idaniloju ninu ara rẹ, laisi irẹwẹsi, iyemeji, ibẹru ati ifoya, pẹlu imọ wipe ohungbogbo ni ṣiṣẹ nipa agbara ati ore-ọfẹ Ọlọrun. (Gẹnẹsisi 18:14)

Ẹyin ara mi ninu Oluwa, agbara aṣe ati ore-ọfẹ nlanla ni o wa fun emi ati iwọ gẹgẹbi obinrin – ni ọgbọn, imọ ati ete lati tunṣe tabi ṣe idakeji rẹ. Ati ni pataki lati mu awọn Ade-ori wa ṣe eyiti ọkan wa nfẹ fun ogo Ọlọrun.

Mo beere: bawo ni iwọ ati emi ṣe nlo ore-ọfe yi gẹgẹbi ọrun ti o gbe Ade-ori wa ro ti o si ndari Ade-ori bẹẹ si ibiti ọ yẹ.

Gẹgẹbi obinrin ti Ẹlẹda da lati iha awọn arakunrin wa, ẹ jeki a beere lọwọ Ọlọrun; agbara ati ore-ọfe lati maa ṣe ife RẸ: eyiti yio mu wa jẹ oluranlowo tootọ fun awọn Ade-ori wa to bẹẹ gẹ ti ẹbi wa yio maa rin ni ọna imọlẹ, iye, otitọ ati ododo ọrọ RẸ lati maa jẹ apẹrẹ ati awokọṣe rere lawujọ iran ẹniyan.

Larin awọn Akikanju Akoni Akin-Obinrin mejeji wọnyi ni a ti le ri awọn ẹkọ pataki wọnyi kọ ni aridaju.
– Akọni loju ija ni awọn aṣayan ẹmi na.
– Wọn ni igbagbọ ninu ara wọn.
– Wọn jẹ amoye ati Ọjọgbon ninu ero ati iṣe wọn ninu ile, nibi isẹ ati ni ile ijọsin.
– Wọn jọwọ ara wọn sile fun iṣẹ Ọlọrun ati iwulo fun iran eniyan.
– Wọn gbẹkẹle Ọlọrun wọn yatọ si ẹran ara wọn.

Ẹyin ara mi ninu Oluwa, akoko ti to lati fi awọn ohun idiwọ bi arankan, ati tẹmbẹlẹkun ṣilẹ ki a si jẹ ipe naa lotitọ ati lododo. Ọlọrun to pe wa: Oun lo yan wa. Oun na lo ṣe wa logo pẹlu agbara imọlẹ RẸ fun idande ati irapada ẹda eniyan gbọgbo lode aiye. Ninu iṣẹ iriju wa yi ni awa ni ohun amuyangan gẹgẹbi ayanfe, ọrẹ Ọlọrun, ọmọlọju ati ẹni mimọ RẸ ti isalẹ.

Adura mi ni wipe: ki Ọlọrun gba iṣakoso aiye wa: ki O si fi agbara Ẹmi mimọ ati ore-ọfẹ RẸ fun wa lati le ṣe ojuṣe wa de oju ami ni kikun. Amin.

Ogo ni fun Ọlọrun Baba, Ọmọ ati Ẹmi Mimọ lai ati lailai. Amin.

NJẸ JESU ỌLỌRUN ALAGBARA JULỌ NI BI?

“ Jesu bi wọn lere wipe ṣugbọn tali ẹyin fi mi pe?” (Matthew 16:15)

Ireti Ọlọrun si awa ẹda ọwọ Rẹ ni wipe ki a le ṣe ohun gbogbo gẹgẹbi ifẹ ati aṣẹ Rẹ, ani lati mọ otitọ Rẹ, otitọ yi yio si sọ wa di ominira. (John 8:32)

Jesu Kristi ti kalarẹ fi apẹrẹ rere lelẹ ni igba ti oun wa laiye pe gbogbo iyin ati ogo ti OLODUMARE ni, Eni ti kin pin ogo Rẹ pẹlu ẹnikẹni, to ba ri bẹ, e ha ti ṣe ti awa ẹda enia, paapa awa kristiani ọmọ lẹhin krsiti nṣe aṣiṣe bi eyi? To bẹẹ gẹ ti pupọ ninu awọn ijọ Ọlọrun ti sọ Jesu Kristi di Ọlọrun Alagbara julọ. Gẹgẹbi gbolohun akọkọ, Jesu bi wa lẹkan si, “ Ta li ẹnyin nfi mi pe?

Ninu aimọ otitọ, ọpọ ninu awọn ẹlẹsin onigbagbọ ati amoye ni ode oni, papa esin igbalode ti gbe Jesu larugẹ gẹgẹbi Ọlọrun Agbaiye. Nipasẹ iṣe bayi eyi ko dun mọ Ọlọrun ninu rara, ati ọmọ bibi rẹ kanṣoṣo Jesu Kristi. Iwasu yi yio gbiyanju lati fi otitọ han kedere laifi ọta pe de oju ami ni kikun. Ki gbogbo ibukun ti o si rọmọ igbesẹ yi ki o jẹ ti igbega Ọlọrun ati ayọ aiyeraye ti o rọ mọ.

Ọpọlọpọ ni iṣiti nipa ti Ẹmi Mimọ ti yio sii jade fun iṣelogo orukọ Olorun Alagbara julọ laiye ati lọrun.
Kini orisun awọn ohun ti o nfa aṣisọ tabi aṣiṣe laarin awọn ọmọ lẹhin Kristi. A o gbe eyi yẹwo nisisiyi pẹlu alaye lati inu iwe mimọ, Bibeli.

Lotitọ iwe mimọ ṣe alaaye lori eyi ṣugbọn ọpọ ninu awa ọmọ lẹhin Kristi ti fun eyi ni itumọ miran, eyi ti ko peye.
IKINI – Isiah 9:6 “Nitoriti a bi ọmọ kan fun wa, a fi ọmọkunrin kan fun wa, ijọba yio si wa li ejika rẹ, a o si ma pe orukọ rẹ ni iyanu, Oludamọran, Ọlọrun Alagbara, Baba Aiyeraiye, ọmọ Alade Alafia.”

EKEJI – John 1 vs 1 – 4 & vs 14. – “Li atetekọṣe li ọrọ wa, ọrọ si wa pẹlu Ọlọrun, Ọlọrun si li ọrọ na. Oun na li o wa li atetekọṣe pẹlu Ọlọrun. Nipase rẹ li a ti da ohun gbogbo, lẹhin rẹ a ko si da ohun kan ninu ohun ti a da. Ninu rẹ ni iye wa, iye na si ni imọlẹ araiye. Ọrọ na si di ara, oun si mba wa gbe, (awa si nwo ogo rẹ, ogo bi ti ọmọ bibi kanṣoṣo lati ọdọ Baba wa) o kun fun ore-ọfẹ ati otitọ.”

ẸKẸTA – Itumọ ti ko tọna, ti awon ijọ ọmọ lẹhin Kristi fi ntumọ Mẹtalọkan gẹgẹbi Ọlọrun Baba, Ọlọrun Ọmọ, ati Ọlọrun Ẹmi Mimọ.

Ti a ba gbe gbogbo awọn akọsilẹ yi yẹwo finifini, o ṣeeṣe ki awọn kan ninu wa dahun ibere akọkọ wipe Jesu Kristi ni Ọlọrun Agbaiye. Ko yẹ ki eyi ri bẹ. Awọn akọsilẹ yi, afihan ni wọn jẹ fun Woli Isiah ati Johaanu. Nitori iṣẹ ribiribi ati iṣẹ pataki ti Jesu Kristi wa ṣe lode aiye, ani tita ẹjẹ rẹ iyebiye silẹ lori oke kalfari fun irapada gbogbo awa ẹda enia. Ọlọrun da Jesu Kristi lọla pẹlu gbogbo ore-ofe ati aṣẹ Rẹ lati lo wọn gẹgẹbi Ọlọrun tikalarẹ ṣe nlo wọn. Ẹ jẹ ki a ṣe akiyesi eyi bi a ṣe ntẹsiwaju ninu iwasu yi.

Ti Baba nla wa Adaamu ko ba ṣi ẹsẹ gbe ni ọgba Edẹni ki yio si idi fun Ọlọrun lati ran ọmọ bibi Rẹ kanṣoṣo (Jesu Kristi) lati wa saiye fun iṣẹ-irapada. Bi Ọlọrun ṣe da emi ati iwọ ni aworan ara Rẹ pẹlu gbogbo ore-ọfẹ ati aṣẹ Rẹ lati jọba lori gbogbo iṣẹ ọwọ Rẹ, bẹẹ gẹgẹ ni Jesu Kristi jẹ apẹrẹ ifẹ nla Ẹlẹdẹ wa. Ifẹ nla lati ọdọ Ọlọrun ni eyi jẹ si iran enia, Jesu Kristi si ni apẹrẹ ife nla naa. Ṣe o wa tọna fun wa lati maa sọ wipe ọmọ Rẹ ati ẹda ọwọ Rẹ ti o ran wa saiye ti di Ọlọrun ti kalarẹ bi? Aṣisọ nla ni eyi.

Ọlọrun ọkanṣoṣo ni Oluda, Olugbọ ati Oluṣe ohungbogbo. Oun A ma bẹ awọn eniyan Rẹ wo lore-koore, ṣugbọn Ẹmi ni, ko si ẹniti o fi oju koo ri. Idi rẹ ti Oun ṣe ran ọmọ bibi Remẹ kanṣoṣo – Jesu Kristi wa ni aworan ara Rẹ lati fi ifẹ, agbara ati titobi nla Rmẹ han si iran enia. Ẹmi Mimo, eyi ti Ẹlẹda fi si inu enia, ni agbara ti o nmu ọmọ enia le ṣe ifẹ Baba rẹ ninu irin ajo rẹ ni ode aiye.


Nitorina, gẹgẹbi ofin ikini – “Iwọ ko gbọdọ ni Ọlọrun miran pẹlu Mi.” Ti o ba ribẹ, aṣiṣọ gbaa ni ki a maa wipe: Ọlọrun Baba, Ọlọrun Ọmọ ati Ọlọrun Ẹmi Mimo. Nitoripe Ọlọrun ko pe mẹta, ọkansmṣosmṣo ni.
Jesu Kristi – ọmọ Ọlọrun ati Ẹmi Mimọ, iṣẹ ọwọ Ọlọrun ni awọn mejeji, OUN si ni Oluda wọn, ọdọ Rẹ ni awọn mejeji ti ṣan wa. Ọlọrun nikan ni Ẹni ti a koda. Ti a ba gbe aworan ila mẹta ti a kan papọ yẹwo (triangle), a o ri wipe:
Baba ni O wa li oke ṣonṣo aworan yi, Ẹmi Mimọ ati Jesu Kristi (ọmọ) li wọn wa ni apa osi ati apa ọtun li abẹ ṣonṣo oke yi. Eyi fi han wipe Ẹmi Mimo ati Jesu Kristi ko dọgba pẹlu Ọlọrun rara bi o tilẹ jẹ wipe awọn mẹtẹta nṣiṣẹ pọ, wọn si wọ inu ara wọn gẹgẹbi ọkan. Ibaṣepọ wọn duro laisi ifi ara gbara, tabi ijowu tabi ọtẹ. Ọlọrun nikan ni Oluda, O si da awọn meji iyoku lọla agbara ati aṣẹ Rẹ ti mbẹ ninu ỌRỌ fun Igbekele ati iselogo Remẹ nikan.

Eyi fi han pe, Ọlọrun Baba ngbe ninu Kristi ati Ẹmi Mimọ, bakanna ni Jesu Kristi ati Ẹmi Mimọ ngbe ninu Ọlọrun Baba (John 10 vs 38), ikana ni wọn lati atetekọṣe ki Ọlọrun to da aiye.
Nigba ti asiko to, O ran Jesu Kristi wa fun iṣẹ irapada, lẹhin ipari iṣẹ irapada ti Ọmọ Rẹ ṣe, O ran Ẹmi Mimọ wa lati tẹsiwaju nibi ti Jesu ti pari iṣẹ tirẹ. Ẹ jẹ ki a ṣe akiyesi eyi bakanna.

A o tẹsiwaju nissisiyi, lati gbe yẹwo, awọn apẹrẹ akọsilẹ lati inu iwe mimọ, paapaa awon ọrọ eyi ti o ti ẹnu Jesu Kristi jade ni igba ti o wa lode aiye, nipa titobi Ọlọrun alagbara julọ. Yooba bọ, wọn ni, a ko le mo otitọ ọrọ ju ẹniti ọrọ bẹẹ ti fọ jade.

Ekini – Matthew 28 : 18 – “Jesu si wá, o si sọ fun wọn, wipe, Gbogbo agbara li ọrun ati li aiye li a fifun mi.” Mo beere tani o fun Jesu Kristi ni agbara yi? Ko sa fun ara rẹ, abi? Bikoṣe Ọlọrun Baba Rẹ.

Ekeji – Johannu 10:36 – “Ẹnyin ha nwi niti ẹniti Baba yà si mimọ́, ti o si rán si aiye pe, Iwọ nsọrọ-odi, nitoriti mo wipe Ọmọ Ọlọrun ni mi?”
Jesu Kristi tikalarẹ fidi otitọ mulẹ pe Ọlọrun Baba rẹ li O ran oun wa gegebi ọmọ Ọkọrun.

Ẹkẹta – Marku 10:18 – Jesu si wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ fi npè mi li ẹni rere? ẹni rere kan ko si bikoṣe ẹnikan, eyini li Ọlọrun.” E yi tun fi han pe Ọlọrun nikan ni ẹni rere. Ti o ba jẹ pe Jesu Kristi ni Ọlọrun, oun ko ni sẹ ara rẹ pe ẹni rere kọ ni oun.

Ẹkẹrin: Matteu 16 vs 15 – 17 – “O bi wọn lẽre, wipe, Ṣugbọn tali ẹnyin nfi mi pè? Simoni Peteru dahùn, wipe, Kristi, Ọmọ Ọlọrun alãye ni iwọ iṣe. Jesu si dahùn o si wi fun u pe, Alabukun-fun ni iwọ Simoni Ọmọ Jona: ki iṣe ẹran ara ati ẹ̀jẹ li o sá fi eyi hàn ọ, ṣugbọn Baba mi ti mbẹ li ọrun.” Eyi fi han kedere pe ẹran ara ati ẹjẹ ninu ẹda enia le mu ọmọ enia ṣe se aṣiṣe lati pe Jesu ni Ọlọrun, ṣugbọn Ọlọrun ti kalarẹ nipa iranlọwọ Ẹmi Mimọ ni O fi otitọ ipo Jesu Kristi han Peteru. Otito yi ni Jesu Kristi tun fi idire mulẹ pe Oun ki iṣe Ọlọrun.

Ẹkarun – Matteu 26:39 – “O si lọ siwaju diẹ, o si dojubolẹ o si ngbadura, wipe, Baba mi, bi o ba le ṣe, jẹ ki ago yi ki o kọja kuro lori mi, ṣugbọn kì í ṣe bi emi ti nfẹ, bikoṣe bi iwọ ti fẹ.” Jesu Kristi nipa gbolohun yi tun fi idimulẹ otitọ pe Ọlọrun ni Baba rẹ ani alagbara julọ laiye ati lọrun.

Ẹkẹfa : kolosse 1, 13 – 15 – “Ẹniti o ti gbà wa kuro lọwọ agbara òkunkun, ti o si ṣi wa nipo sinu ijọba ayanfẹ ọmọ rẹ̀: Ninu ẹniti awa ni idande nipa ẹ̀jẹ rẹ̀, ani idariji ẹ̀ṣẹ: Ẹniti iṣe aworan Ọlọrun ti a kò ri, akọbi gbogbo ẹda:” Itumọ eyi ni wipe Ọlọrun ko ran ara Rẹ wa saiye, ọmọ Rẹ Jesu lo ran wa, ẹniti oun si ti jogun ijọba Rẹ fun bakanna gẹgẹbi akọbi gbogbo ẹda ọwọ Rẹ.”

Ekeje – Matteu 24:36 – “Ṣugbọn niti ọjọ ati wakati na, kò si ẹnikan ti o mọ̀ ọ, awọn angẹli ọrun kò tilẹ mọ̀ ọ, bikoṣe Baba mi nikanṣoṣo.” E yi tun fi han wa kedere pe, Jesu krisiti ki iṣe Ọlọrun bi bẹ kọ, yio mọ wakati tabi ọjọ naa.

Ẹkẹjọ : Johannu 14 : 28 – “Ẹnyin sá ti gbọ́ bi mo ti wi fun nyin pe, Emi nlọ, emi ó si tọ̀ nyin wá. Ibaṣepe ẹnyin fẹràn mi, ẹnyin iba yọ̀ nitori emi nlọ sọdọ Baba: nitori Baba mi tobi jù mi lọ.”
Bakanna, gbolohun ọrọ yi lati ẹnu Jesu Kristi tun fi han pe oun ki iṣe Ọlọrun.

Ẹkẹsan – Johannu 20:17 – “Jesu wi fun u pe, Máṣe fi ọwọ́ kàn mi; nitoriti emi kò ti igòke lọ sọdọ Baba mi: ṣugbọn lọ sọdọ awọn arakunrin mi, si wi fun wọn pe, Emi ngòke lọ sọdọ Baba mi, ati Baba nyin; ati sọdọ Ọlọrun mi, ati Ọlọrun nyin.”

Ẹkẹwa: Matteu 27 vs 45 – 46 : “Lati wakati kẹfa, ni òkunkun ṣú bò gbogbo ilẹ titi o fi di wakati kẹsan. Niwọn wakati kẹsan ni Jesu si kigbe li ohùn rara wipe, Eli, Eli, lama sabaktani? eyini ni, Ọlọrun mi, Ọlọrun mi, ẽṣe ti iwọ fi kọ̀ mi silẹ?”
Otitọ gbolohun lati ẹnu Jesu Kristi fi han kedere pe Ọlọrun nikan ni alagbara julọ, Ẹniti Jesu Kristi ke pe fun iranlọwọ ni ori igi agbelebu.

Ikọkanla: Romu 8:34 – “Tali ẹniti ndẹbi? Ihaṣe Kristi Jesu ti o kú, ki a sa kuku wipe ti a ti ji dide kuro ninu okú, ẹniti o si wà li ọwọ́ ọtun Ọlọrun, ti o si mbẹ̀bẹ fun wa?” Ẹ jẹ ki a ṣe akiyesi eyi bakanna.

Ekejila : Luku 23 v34 – “Jesu si wipe, Baba, darijì wọn; nitoriti nwọn kò mọ̀ ohun ti nwọn nṣe. Nwọn si pín aṣọ rẹ̀ lãrin ara wọn, nwọn di ìbo rẹ̀.”

Ẹkẹtala – Johannu 6 v 57 – “Gẹgẹ bi Baba alãye ti rán mi, ti emi si ye nipa Baba: gẹgẹ bẹ̃li ẹniti o jẹ mi, on pẹlu yio yè nipa mi.”

ẸKẹdogun: 1Korinti 11 : 3 – “Ṣugbọn mo fẹ ki ẹnyin ki o mọ̀ pe, Kristi li ori olukuluku ọkunrin; ori obinrin si li ọkọ rẹ̀; ati ori Kristi si li Ọlọrun.”
Li otitọ ati ni ododo Aposteli Paul fi han wa kedere pe Jesu Kristi ni olori, ẹniti iṣe Ọlọrun Baba Rẹ. Ni idi eyi ko gbọdọ si idi fun aṣiṣe laarin awọn ọmọ lẹhin Jesu Kristi pe oun ni Ọlọrun Alagbara julọ. Aṣisọ ni eyi.

ẸKẹrindinlogun – Matteu 3 vs 17 – “Si kiyesi i, ohùn kan lati ọrun wá, nwipe, Eyí ni ayanfẹ ọmọ mi, ẹniti inu mi dùn si gidigidi.”
Ohun Ọlọrun Baba Jesu Kristi li eyi. Eyi tun fi idi rẹ mulẹ pe Ọlrun lo ran Jesu Kristi ọmọ bibi Rẹ kanṣoṣo wa si ile aiye fun iṣẹ irapada.

Ẹkẹtadinlogun – Matteu 6 vs 9 – 13 – “Nitorina bayi ni ki ẹnyin mã gbadura: Baba wa ti mbẹ li ọrun; Ki a bọ̀wọ fun orukọ rẹ. Ki ijọba rẹ de; Ifẹ tirẹ ni ki a ṣe, bi ti ọrun, bẹ̃ni li aiye…..”
Mo bere to ba jẹ pe Jesu Kristi ni Ọlọrun, eeṣe ti oun ki nkọ ko awa enia lati ko ju si ẹlomiran loke lati gbọ ebe adura won, nigbati oun tikalarẹ wa pẹlu wọn ni asiko bẹ?

Enyin ara ati gbogbo awọn ọmọ lẹhin Kristi, ni ikadi ọrọ isiti yi, pelu gbogbo itọkasi wọnyi ko yẹ ki ariyanjiyan tabi aṣiṣe tabi aṣisọ tun maa fara han mọ nipa titobi Ọlọrun Alagbara. Jesu Kristi, Olugbala ati Oluwa wa ki iṣe Ọlọrun bikoṣe ọmọ bibi Rẹ kanṣoṣo ti o jọwọ ara rẹ lati wa si ile aiye lati mu iran enia pada si ọdọ Baba rẹ.

Aṣisọ patapata ni ki a ma wipe Ọlọrun di enia nipasẹ Jesu Krsiti. Eyi ti o nfi idimulẹ laarin ijọ Ọlọrun, bẹẹ ni awa kan nkọ eyi li orin ninu isin.

Fun imọ wa si, awọn ọmọ Ọlọrun jẹ mẹrindinlogun (16) ni iye, eyi ti Jesu Kristi jẹ ọkan ninu wọn. Ṣugbọn nitori iṣẹ iyebiye ti nṣe ti irapada awa ọmọ enia ti Jesu ṣe, ipo Jesu Kristi tayọ gbogbo awọn ọmọ Ọlọrun ti o ku.
Nigbati Olorun so wipe tali oun yio ran, tali yio lọ fun iṣẹ naa? Gbolohun yi, Ọlọrun dari rẹ si awon ọmọ Rẹ ni, ki iṣe si awọn angẹli Rẹ.
Gẹgẹbi awọn ọmọ Israẹli ti ṣe aṣiṣe ti wọn pe Mose ni Ọlọrun ni aginju nitori iṣẹ iyanu ti Ẹlẹda gba ọwọ rẹ ṣe, bakanna ni aṣiṣe awa ọmọ lẹhin Kristi ti ode oni ti a npe Jesu Kristi li Ọlọrun.

Ẹ jẹ ki a yara lati ṣe atunṣe nitoripe eyi ko dun mọ Jesu Kristi ninu rara, o nsi bẹbẹ fun wa niwaju itẹ aanu fun idariji lati ọwọ Baba rẹ nitoripe Ọlọrun ojowu ni Baba rẹ, ẹniti ki yio pin ogo Rẹ pẹlu ẹnikẹni.
Bakanna E ma ṣi mi gbọ, mi o ko iyan ọmọ Rẹ Jesu Kristi kere rara. Fun iṣẹ ribi ribi ti o ṣe, fun iṣẹ irapada ati igbala ti oun jogun fun iran enia, o yẹ ki a ma dupẹ gidigidi lọwọ rẹ, ki a si ma gbe ohun ati Baba rẹ ga. Ki Ọlọrun ki o ran wa lọwọ.

Ọlọrun Alagbara julọ ni, gbogbo ibi ni Oun wa, oju Rẹ si ka ohun gbogbo. Ko ni afiwe, ko lọga. Titobi Rẹ ko ṣe fi ẹnu sọ tabi ṣe apejuwe, bakanna Oun tikalarẹ li O ngbe inu emi ati iwọ. Ki Ọlọrun ki o bu si ọrọ Rẹ. Amin.

Read more