IDAJỌ ỌLỌRUN

ricardo-gomez-angel-282325-unsplash_1_50

Heb 9:27 “Niwọn bi a si ti fi lelẹ fun gbogbo enia lati kú lẹ̃kanṣoṣo, ṣugbọn lẹhin eyi idajọ:”

Lati igba iwaṣẹ ni Ọlọrun ti jẹ Oludajọ fun gbogbo iṣẹ ọwọ Rẹ. A gbọdọ mọ bawo, igbawo ati idi pataki ti Ẹlẹda fi nda ẹjọ. Eyi yio jẹ atọna fun wa lati huwa tabi gbe igbesẹ ti a o fi jinna si ibinu Ẹlẹda.
“Ṣugbọn awa mo pe idajọ Ọlọrun jẹ gẹgẹbi otitọ si gbogbo awọn ti o nṣe iru ohun wọnyi” Rome 2:2. (Eniyan ko gbọdọ da enikeji rẹ lẹjọ).

“Kiyesi i, Emi mbọ kan kan, ere mi si mbẹ pẹlu mi lati san an fun olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ rẹ yoo ti ri” – Ifihan 22:12

Gbogbo ẹda ni yio gba ere iṣẹ ọwọ rẹ. Ko si ibi ti a lee sa si. ko si ojuṣaaju. Yoruba bọ, nwọn ni “O ta ọfa s’oke, o yi odo bo ori, bi Oba aiye ko ri ọ, Ọba oke nwo ọ”.

Awọn Musulumi gbagbọ wipe igbaradi fun igbe aye titun ni eyiti a wa yii. Ọjọ mbọ ti a o pa aiye yi rẹ, ti awọn oku yio ji dide fun idajọ lati ọwọ Ẹlẹda. Wọn gbagbọ wipe awọn eniyan yio gba idajọ gẹgẹbi ohun ti nwọn gbagbọ ati iṣe nwọn. Awọn ti o gba Ọlọrun gbọ ati Muhammed bi ojiṣẹ Rẹ, nikan ni nwọn gbagbọ wipe yio wọ ọrun rere (Aljana).

Ninu iwe Mimọ Bibeli, awa Kristiani ka a bi Ẹlẹda ṣe nṣe idajọ lati ibẹrẹ pẹpẹ aiye. Adamu, Efa ati ejo gba idajọ ni’gbati nwọn l’odi si ifẹ Ẹlẹda (Gen. 3 :14-19). Kaini naa fi ara gba ni’gbati o ṣe iku pa Abẹli arakunrin rẹ. Oluwa si ge egun fun un. (Genesisi 4:11-12).
Nigbati Ọlọrun Pinnu lati fi iya jẹ Sodomu ati Gomorrah fun ẹṣẹ wọn, bi o tilẹ jẹ wipe Abrahamu bẹbẹ fun aanu, sibẹ, ko si olododo mẹwa pere, ti o le mu ki Ẹlẹda yi ipinnu Rẹ pada. (Genesis 18:20-25)

Idajọ Ẹlẹda wipe; ida ko ni kuro ninu ile Dafidi, ni ‘nja l’ori awọn ọmọ Israeli titi di oni, bi o tilẹ jẹ wipe nwọn nṣẹ’gun ni ọpọ igba.

Ninu majẹmu titun (Igba keji) Ọlọrun ran Jesu Kristi wa si aiye lati wa kọ wa ni Ifẹ Ọlọrun. Lati fi ọna iye han wa. O wa, O ṣe iṣẹ Rẹ ni aṣeyege, O si pada si ọdọ Baba Rẹ. Sibẹ, ẹda kọ lati mọ riri Ọlọrun ati l’ati pa ofin Rẹ mọ.
Pupọ ninu owe ti Jesu pa ṣe afiwe idajọ Ẹlẹda, gẹgẹ bi igbesẹ fun atunṣe wa. O fihan wa bi ẹda ṣe nlo id’anu rẹ.
Fun apẹrẹ: – Talẹnti (Matt 25:14-30). Oṣiṣẹ ninu ọgba ajara (Matt. 20: 1-16). Wundia mẹwa (Matt. 25:1-13).

Iku ni ere ẹṣẹ, ati lẹhin iku, idajọ mbẹ: Gbogbo eniyan ni o ti ṣẹ, ti o si ti kuna ogo Ọlọrun. Gbogbo wa ni a ti da agbada iku, ti a o si gba idajọ. Ọpọlọpọ ẹda tilẹ maa ngba idajọ ni ode aiye, ki iku to de.

Ninu Agbo Mimọ ti igba kẹta, igbagbọ wa, bi awọn ogun ọrun ṣe fi bọ wa ni wipe; Gbogbo oku ni yio gba idajọ. Idajọ yi bẹrẹ lẹhin ogoji ọjọ ti a ba fi aiye silẹ. Ayẹwo yio wa fun akọsilẹ iṣẹ ti a gbe ile aiye ṣe. Lati mọ boya ẹmi yi peregede lati darapọ pẹlu awọn Mimọ lati maa yin Ẹlẹda ni itẹ Ogo, tabi, yio tun pada wa lati wa ṣe atunṣe awọn aṣiṣe rẹ ni aiye yi.
O niye igba ti ẹda lee pada wa fun atunṣe yi, ki o to wa gba idajọ Ẹlẹda ikẹhin ni kikun.

Ọlọrun da gbogbo ẹda enia lati sin Oun; O pe awa kan sinu Agbo Mimọ yi, O si fun gbogbo iran enia ni iṣẹ lati ṣe ki a lee ni ipa ti o j’ọju ni igbe aiye wa ni ode aiye. A nilati fi ọna ijọba Ọlọrun han awọn ẹda miran ni ode aye ninu ero, ọrọ ati iṣe wa. A ni lati wa awọn ti ko ti i ni imọ nipa ohun ti Ẹlẹda nreti lọwọ ẹda ọwọ Rẹ, ki a si fi imọ yi bọ wọn.

A ni lati fi ifẹ han si ọmọlakeji wa. A ko gbọdọ bẹru tabi tiju lati jẹki awọn eniyan mọ wipe ọmọ Agbo Mimọ ni a jẹ. A ni lati tọ awọn eniyan si ṣiṣe ifẹ Ẹlẹda.
Ọlọrun Onidajọ gbogbo ẹda ọwọ Rẹ ni o nṣe idajọ. Oun a maa ṣe idajọ ododo, O si pọ ni Aanu.
Ki Ẹlẹda, ninu aṣẹ ati oore-ọfẹ Rẹ ṣe wa yẹ, ki gbogbo wa le ri aanu gba ni ọjọ idajọ. Amin.

Leave a Reply