Oore-ọfẹ! Ohun
Adun ni l’eti wa;
Gbo’un-gbo’un rẹ y’o gba ọrun kan,
Aiye y’o gbọ pẹlu.
Oore-ọfẹ ṣa
N’igbẹkẹle mi;
Jesu ku fun araiye,
O ku fun mi pẹlu.
Awọn kristiani maa nlo ọrọ yi – (oore-ọfe) laibikita, nitori nwọn ro wipe awọn ti mọ ohungbogbo ti nwọn ni lati mọ nipa oore-ọfẹ. Oore-ọfẹ jẹ ohun oju rere ti ko tọ si wa lati ọdọ Ọlọrun. Lootọ ati ni ododo, ṣe oju rere ti ko tọ si wa ni oore-ọfẹ jẹ?
Aposteli Paulu ninu iwe rẹ si awọn ara Romu, ori ikarun ẹsẹ ogun (Romans 5:20) kọ wa pe “nibiti ẹṣẹ ba ti npọ sii, oore-ọfẹ a maa pọ sii pẹlu.” Ṣugbọn oun yara lati sọ pe eyi ki nṣe iwunni lori lati maa gbe igbe aiye aibikita – kini ki ati wi nigba naa? Ṣe ki a maa gbe ninu ẹṣẹ ki oore-ọfẹ le maa pọ sii bi? Ki eyi ki o maa ṣe ri bẹẹ rara.
Eeṣe ti awa ti a ti ku si ẹṣẹ, maa gbe ninu rẹ bi (ẹṣẹ)? Iwe Romu ori ikẹfa ẹsẹ ikini si ekeji (Romans 6:1-2) beere lọwọ wa – “kinni oore-ọfẹ Ọlọrun ati pe kinni eyi jẹ si wa? Ni titumọ oore-ọfẹ Ọlọrun, ngo gbiyanju lati lo awọn ohun ti onkọwe kan ti kọ silẹ.
Oore jẹ ekinni iwa ti o rọ mọ Ọlọrun ti o si njẹ iwa ara ọmọ enia. Idajọ Ọlọrun; Iwa Mimọ Ọlọrun; Ọlọrun ti agbara Rẹ wa ni ibi gbogbo; ti imọlẹ ijinlẹ Rẹ si kari aiye; gbogbo iwọnyi jẹ iwa àmọ̀mọ́ ni Ọlọrun, ṣugbọn oore-ọfẹ duro gedegbe, ti oun si jẹ apakan iwa Ọlọrun ti o farahan ninu majẹmu lailai.
Awọn ọmọ Ọlọrun bi Dafidi nwo Ọlọrun bi Oloore-ọfẹ. Iwe orin Psalm ori kẹta-le-lọgọrun (Psalm:103), kun fun iyin ati idupẹ, eyi ti o nfi oore-ọfẹ Ọlọrun han.
Ohun ti o fi han gbangba oore-ọfẹ Ọlọrun ni wiwa si aiye Jesu Kristi, ti Oun si ku fun awa ẹlẹṣẹ, ti a si de ni ade iṣelogo, Heberu Ori ikeji ẹsẹ ikẹsan. Igbala wa jẹ pipọ ninu ọla oore-ọfẹ Rẹ -Efesu Ori ikinni, ẹsẹ ikeje. Ipe wa ninu ominira Ẹlẹda jẹ eyiti ko ṣe iyipada ninu oore-ọfẹ Rẹ, Iwe Galatia Ori ikinni ẹsẹ ikarundinlogun. Idalare, eyi ti o ti inu idajọ wa wipe, awa jẹ ẹni idalare kuro ninu ẹbi ninu i-ṣe Jesu Kristi, eyi jẹ ẹbun oore-ọfẹ. Iwe Romu Ori kẹta ẹsẹ ikẹrinlelogun, ati iwe Titu Ori ikẹta, ẹsẹ ikeje (Titus 3:7).
Ninu apapọ ọrọ Rẹ, gbogbo ẹka iṣẹ igbala ni o jẹ iṣẹ Ẹlẹda (Ọlọrun) fun oore-ọfẹ, eyi ti ki i ṣe iṣẹ ọwọ wa.
Oore-ọfẹ lo kọ
Orukọ mi l’ọrun
Lo fi mi fun Ọd’agutan
To gba iya mi jẹ.
Bi o tilẹ jẹ pe akori Oore-ọfẹ Ọlọrun ni agbelebu oke Kalfari, a le ṣe apejuwe oore-ọfẹ ni oriṣiriṣi ọna.
i) Oore-ọfẹ ti o wọpọ – Eyi ni oore-ọfẹ ti Oun fun gbogbo enia – nitori Oun
mu ki oorun ran sori ẹni ibi ati ẹni ika ati ẹni ire. Oun si nrọ ojo si ori
olododo ati alaiṣododo. Matiu Ori ikarun ẹsẹ ikẹrinlelogoji si ikarundin-ni-
aadọfa. Ọlọrun kun fun oore-ọfẹ lati mu igbala wa fun gbogbo enia nipa sisun idajọ Rẹ siwaju, nipa eyi ti Oun fun wa ni okùn ti ogun fun ironupiwada. –Peteru keji, ori kẹta ẹsẹ ikẹsan.
ii) Oore-ọfẹ igbala –Iṣe Awọn Aposteli Ori ikarundinlogun, ẹsẹ ikọkanla, eyi ti iṣe oore-ọfẹ aabo lori igi agblebu.
iii) Oore-ọfẹ iwẹnumọ – eyi ni oore-ọfẹ ti nṣiṣẹ ninu onigbagbọ ododo lati mu idagba soke, itẹsiwaju ati gbigbọn ninu fifi iwa jọ Kristi.
Inu didun ni awọn ti wọn bẹru lati ya kuro loọna idajọ Rẹ ti nwọn mọ ti nwọn si fẹran ọna Rẹ ti nwọn si npa ododo ati ofin Rẹ mọ, ti nwọn si nṣe wọn.
iv) Oore-ọfẹ iṣẹ, ni oore-ọfẹ ti o gba ọ laaye lati lo ibukun ti ẹmi fun ogo Ọlọrun ati fun ire ati anfaani ọmọ enia.
v) Oore-ọfẹ imuduro – Oore-ọfẹ yi fun enia ni pataki ni imuduro ni akoko wahala ati ijiya.
Oore-ọfẹ nwa wa ri, o ngba wa la, pa wa mọ, dabobo wa, o nsun wa siwaju o si ngba wa laaye lati sin ati lati farada idanwo ati wahala aiye. Irin ajo aiye wa jẹ iranlọwọ at’oke wa. Eyi mu wa wa si ọrọ ai-yẹ tabi iyemeji tabi aini igbagbọ aaye wipe oore-ọfẹ ngbè wa, nitorina a le wa lailo ofin.
AWỌN OFIN ATI OORE-ỌFẸ ỌLỌRUN
Ṣe ki a wipe awọn baba wa ati awọn ẹni igbagbọ igbaani ngbe ninu igbagbọ pe oore-ọfẹ ti o bo ẹṣẹ mọlẹ ati pe ofin ko lagbara kan lori awọn mọ? Ibaṣepọ oore-ọfẹ ati ofin jẹ ọkan ninu awọn ohun ti o nfa rudurudu silẹ laarin awọn onigbagbọ. Awọn onigbagbọ kan gba ara wọn wipe a ko wa labẹ ofin tabi aṣẹ kan nitorina a le gbe igbe aiye bi a ti fẹ. Ṣugbọn Paulu Aposteli ninu iwe rẹ ikinni si awọn ara Kọrinti Ori ikẹẹdogun ẹsẹ ikẹwa: “Ṣugbọn nipa oore-ọfẹ Ọlọrun, mo ri bi mo ti ri, oore-ọfẹ Rẹ ti a fi fun mi, ko si jẹ asan; ṣugbọn mo ṣiṣẹ lọpọlọpọ ju gbogbo wọṅ lọ; ṣugbọn ki i ṣe emi bikoṣẹ oore-ọfẹ Ọlọrun ti o wa pẹlu mi”.
Aposteli Paulu wi nihin pe oore-ọfẹ ko wa laisi ojuṣe ati pe oore-ọfẹ wa fun awọn ayanfẹ Rẹ nipa aniyan, igbiyanju, ero ati i-ṣe wọn. Oore-ọfẹ Ọlọrun to fun awọn tiRẹ ati pe iwọn rẹ a maa kun oju oṣuwọn. Raphael, Anael, Gabriel
Paulu, gẹgẹbi olupolongo oore-ọfẹ Ọlọrun ninu iwe rẹ si awọn ara Romu Ori ikẹta, ẹsẹ ikọkanlelogun si ọkanlelọgbọn ṣe ipari ni ẹsẹ ikọkanlelọgbọn pe: “AWA HA NSỌ OFIN DASAN NIPA IGBAGBỌ BI? KI A MA RI, ṢUGBỌN A NFI OFIN MULẸ.” Oun tẹ siwaju lati sọ ni iwe Romu Ori ikẹfa, ẹsẹ ikinni si ikeji pe “ Njẹ awa o ha ti wi? Ki awa ki o ha joko ninu ẹṣẹ, ki oore-ọfẹ maa pọ sii?
Ninu iwe Romu Ori ikẹfa ẹsẹ ikarundinlogun si ikejidinlogun Paulu tẹsiwaju lati beere pe –“Njẹ kinni? Ki awa ki o ha maa dẹṣẹ, nitoriti awa ko si labẹ ofin, bikoṣe labẹ oore-ọfẹ? ki a ma rii.” Oun polongo nihin nipa aidọgba pe oore-ọfẹ ha mu ojuṣe wa kuro lat bọwọ fun ofin Ọlorun bi?
Ẹkọ mi nipa oore-ọfẹ Ọlọrun kuru pupọ, ṣugbọn eyi ran mi leti nipa aanu Ẹlẹda si awa enia Rẹ. O yẹ ki a mọ pe didara ni ohun gbogbo ti o ba ṣẹlẹ si awa ọmọ enia, ati pe lati ọdọ Ọlọrun Oloore-ọfẹ ni eyi ti wa. O si tun han si mi wipe awọn enia ko bẹru Ọlọrun, nwọn a maa mu Ọlọrun pẹlu aibikita. Wọn tumọ oore-ọfẹ Rẹ gẹgẹbi Ẹni alailagbara ati ifasẹhin idajọ Rẹ gẹgẹbi Ẹniti ko ni idi Pataki lati mu Ileri Rẹ ṣẹ. Awa ọmọ enia ti o npafọ ninu ọna aidọgba ati ẹṣẹ gbogbo, ko ṣe tan lati gba idalẹbi ara wa rara nitori ẹtanjẹ eṣu, nitori ori kunkun ko jẹ ki wọn mọ ọna ati bẹbẹ fun oore-ọfẹ Ọlọrun. Ọlọrun alaanu ni Oun, ti awa ẹlẹṣẹ ba le jẹwọ ẹṣẹ wa, ki a si pe fun igbala kuro ninu ẹṣẹ wa. Oore-ọfẹ Rẹ wa fun emi ati iwọ gẹgẹbi ẹlẹṣẹ. Ewo li o pe wa julọ, ninu ki Oun fi Oore-ọfẹ Rẹ gbọ tiwa tabi ki a kuku gba ere ẹṣẹ wa lẹkun rẹrẹ ninu aiko gba oore-ọfẹ igbala ti Oun fi fun wa?
Ki oore-ọfẹ Ọlọrun to fun wa ninu iwulo rẹ fun wa, ati pe ki awọn enia ri oore-ọfẹ yi ninu wa fun iyin ogo orukọ mimọ Rẹ. Amin.
Jẹki Oore-ọfẹ yi
F’agbara f’n ọkan mi
Ki nle fi gbogbo ipa mi
A t’ọjọ mi fun Ọ.
Oore-ọfẹ ṣa ni igbẹkẹle mi
Jesu ku fun araiye
O ku fun mi pẹlu. Amin.