The Great Divine Holy Order of the Third Era

IMỌ LORI AGBO MIMỌ TI IGBA KẸTA

Agbo Mimọ ti Igba Kẹta yi ni Ọlọrun da silẹ funra tikalara Rẹ ni ọdun 1941, lati fi oye ọrọ Rẹ bọ iran enia bi a ti nsin In lotitọ ati lododo, gẹgẹbi Oun ti pe Abrahamu ti O si ṣiṣẹ pẹlu rẹ ati iran-diran rẹ ni igbani fun ogunlọgọ ọdun. Bi ọdun ti ngori ọdun, bẹẹ ni imọ ati oye ọrọ Ọlọrun njẹ fifi bọ ijọ Rẹ lati ọwọ awọn ogun ọrun ati Ẹmi Mimọ, bẹẹ ni imọ, oye ati ẹkọ ọrọ Rẹ ninu Iwe Mimọ (Bibeli) npeleke si fun ijọ Rẹ.

Agbo Mimọ ti Igba Kẹta duro gẹgẹbi orisun ijinlẹ Mimọ fun ẹkọ ati imọ to ṣọwọn nipa awọn ohun ti ẹmi, ti ko ni abawọn kan. Idi ni eyi ti Ẹlẹda fi pee ni Agbo Mimọ. A le juwe rẹ gẹgẹbi Ile-ẹkọ ti ẹmi fun ijinlẹ imọ ọrọ Ọlọrun lori bi iran enia ṣe nsin Ọlọrun ninu ẹwa iwa mimọ, igbagbọ, ifẹ, igbọran ati otitọ. Aṣiri ijinlẹ ati imọ ti ko wọpọ nipa Ọlọrun, iṣẹda Rẹ ati ohungbogbo ti O da ni njẹ fifi bọ ijọ enia Rẹ ninu Agbo Mimọ, lati mu ijọ enia Rẹ di Ọjọgbọn pipe, ikọ Alufa ati Ẹni-Ọwọ tootọ, ikọ Ajihinrere ati Ojiṣẹ ọrọ Rẹ, Ọlukọni ati ikọ Olutumọ ọrọ Rẹ tootọ, ati irufẹ awọn Ẹni ami ororo ati oṣiṣẹ loriṣiriṣi ọna. Gbogbo ẹniti o ni anfani lati jẹ ọmọ ijọ Ọlọrun yi ni akẹkọ ni ọna ohun-ti-ẹmi, pẹlu eto ẹkọ ijinlẹ ti o peye, eyi ti yio mu ki ẹmi kọọkan duro ni awujọ iran enia gẹgẹbu Ẹni-Ọwọ, Olori-Ẹsin ati Ọba aiye lati ṣe iṣakoso ati idari ninu ẹmi ninu ile, ayika ati lawujọ.

Agbo Mimọ gẹgẹbi orukọ rẹ, jẹ ibi ọwọ julọ, nibiti eto isin mimọ ati ijuba Ẹlẹda ninu irẹlẹ, ọwọ ati ibọwọ fun Ọlọrun, ti njẹ sisọkalẹ lati ọwọ Ẹmi Mimọ wa, lai fakọ si, tabi pidan ati laiṣe karimi.

Agbo Mimọ ki i-ṣe ẹgbẹ okunkun tabi ijọ madaru bi awọn kan ṣe lero, nitori aimọkan wọn; ṣugbọn oun jẹ Ile-ẹkọ to ga julọ ni ti ohun-ẹmi. Aṣọ funfun balau ni aṣọ igunwa fun ijọsin ninu Agbo Mimọ, iwọnyi si gbọdọ jẹ ọgbaọgba ni ẹya ati ni riran fun olukuluku. Ko si wiwọ goolu ẹgba-ọrun, ọwọ ati ẹsẹ tabi ilẹkẹ ati ẹṣọ miran lori aṣọ igunwa yi. Awọn diẹ ti Ẹlẹda yan si ipo Alakoso ati Oye ninu agbo yi ni ore-ọfẹ riran ipele sori aṣọ iginwa wọn, eyi si lati jẹ funfun bakanna. Aṣọ funfun-aṣọ igunwa yi ni a ko gbọdọ wọ jade sita tabi fi rin kiri oju opopona, bikoṣe iyasọtọ fun isin mimọ Ọlọrun nikan, aṣọ igunwa yi ni lati jẹ mimọ ati ailabawọn. 7

Gẹgẹbi akọsilẹ ninu iwe mimọ (Eksodu 31:16-17) ati ni ibamupọ pẹlu aṣẹ Ọlọrun, ọjọ Abamẹta, ọjọ keje ninu ọsẹ ni Agbo Mimọ ya sọtọ fun isin ọjọ isinmi mimọ Ọlọrun. Ore-ọfẹ wa fun awọn diẹ ti wọn nifẹ lati jọsin pẹlu awọn ẹbi wọn ni ile ijọsin miran ni ọjọ aiku, ti nṣe ọjọ kini ọsẹ lati dọgba pẹlu wọn.

Ẹkọ ọrọ Ọlọrun ti o njẹ kikọ ni awọn ile ijọsin miran ni a ko le fi ọwọ rọ sẹhin. Ṣugbọn bi iwọnyi ti dara to, ipele ẹkọ ati imọ akọkọ ni eyi fun arinrin-ajo wa saiye lati mọ nipa ara rẹ, Ọlọrun ati ijọba Rẹ.

Kiki awọn ti wọn nifẹ lati ni imọ kikun nipa Ọlọrun ati iṣẹda Rẹ pẹlu ipinnu lati ṣiṣẹ fun Ọlọrun ni o le jẹ akẹkọ ninu Agbo Mimọ.

Ninu Agbo Mimọ a ko gba laaye jijadu fun ipo, idije, jijẹ-ara-ẹni-lẹsẹ, bibẹbẹ fun ipo tabi nini baba ngbẹjọ ni yiyan awọn oloye si ipo. Ọlọrun nikan ninu eto mimọ Rẹ lati ọwọ Ẹmi Mimọ wa ni O nyan awọn ti o tọ si ipo kan tabi omiran gẹgẹbi ifẹ ati aṣẹ Rẹ.

Imọ lagbara pupọpupọ, o si nfi agbara fun ẹda, sibẹ ẹda le lo agbara bayi lati ṣe rere tabi idakeji rẹ. Otitọ ọrọ Rẹ ni eyi, ti ohun kan ko le yi pada.

Ọrọ rikiṣi ati keeta awọn enia ni ki yio tu irun kan lara awa ti Ọlọrun fi ifẹ Rẹ pe sinu Agbo Mimọ Rẹ, nitoriti atilẹhin Rẹ ni yio maa jẹ ohun iwuri fun wa ninu iṣẹ iriju wa lati fi imọ ati oye ọrọ Rẹ bọ awọn eniyan fun idande ati irapada orilẹ ede aiye gbogbo.

Iriri wa ni wipe, bi enia ṣe rere tabi aburu, o di dandan ki ọrọ ẹhin wa nipa i-ṣe ẹda gbogbo bẹ lati ọdọ awọn ti ko ni oye to, nitorina li a ṣe duro lori ipinnu ati ifẹ ni ṣiṣe eyiti Ọlọrun yan fun wa lati ṣe fun idande ati irapada iran-eniyan titi gẹgẹbi aṣẹ Ẹlẹda wa.

Latest Sermons

Sermons

GRACE AND LAW OF GOD

Grace in general terms is simply God’s unmerited favour and undeserved spiritual blessings. Favour we could say is goodwill, benevolent regard; a kind or helpful deed. I would go further to say, Grace is the manifestation of the love of

Read More »
Sermons

IS JESUS ALMIGHTY GOD?

“Jesus asked His disciples thus” “But whom say ye that I am? Matthew 16:15. It is the expectation of the Almighty God that man as the crown of His creation will know the truth and the truth will set such

Read More »
Sermons

Diligence and Fortitude

The American election was a real eye opener, the first female American woman to contest the position of the President of USA was described by her opponent to be determined, tenacious, courageous, fearless, hardworking, showing care & conscientiousness, diligent to

Read More »