RUTU GẸGẸ BI AWOKỌṢE. (IWE RUTU)
Rutu 1:16: “Rutu si wipe, Máṣe rọ̀ mi lati fi ọ silẹ, tabi lati pada kuro lẹhin rẹ: nitori ibiti iwọ ba lọ, li emi o lọ; ibiti iwọ ba si wọ̀, li emi o wọ̀: awọn enia rẹ ni yio ma ṣe enia mi, Ọlọrun rẹ ni yio si ma ṣe Ọlọrun mi:”.
- Elimeleki jẹ ara Betilẹhẹmu. Aya rẹ, (Naomi) bi ọmọ ọkunrin meji – Maloni ati kilioni, fun un. Nigbati iyan mu ni Bẹtilẹhẹmu- juda, awọn ẹbi yi ko ara wọn lọ si ile Moabu lati lọ ṣe atipo, ki wọn ba le ri onjẹ jẹ.
- Awọn ọmọ rẹ mejeji fẹ iyawo – Orpa ati Rutu. Awọn ara Moabu ni awọn iyawo wọnyi. Aboriṣa ni wọn. Wọn ko si bimọ.
- Lẹhin ọdun mẹwa, Elimeleki ati awọn ọmọ rẹ mejeeji ku. O si wa ku Naomi, Orpa ati Rutu. Asiko yii ni irohin wa wipe, iyan ti ka’sẹ ni ilẹ Bẹtilẹhẹmu.
- Naomi nfẹ pada si Bẹtilẹhẹmu, o si rọ awon aya ọmọ rẹ mejeji lati pada si ọdọ awọn obi wọn ki wọn ba lee fẹ ọkọ titun. Orpa gba imọran yii, o si pada si ile rẹ, ṣugbọn Rutu taku wipe oun yoo ba iya-ọkọ oun pada si ile rẹ ni Bẹtilẹhẹmu.
- Rutu fi ẹsin ati aṣa ati ede rẹ silẹ, o si tẹle iya-ọkọ rẹ. Ọpọ ni ọrọ ti awọn ara ilu nwi nipa Naomi ati Rutu, ṣugbọn eyi ko di Rutu lọwọ.
- Asiko yi jẹ igba ikore ọka baali akọkọ, lẹhin iyan – Rutu sọ fun Naomi wipe oun yio lọ si oko lati lo ṣa ẹgbọnsilẹ ọka ki wọn ba le ri onjẹ jẹ. Rutu ṣe oriire lati lọ si ọgba Boasi eniti i- se ibatan baba ọkọ rẹ ti o ti di oloogbe. Boasi wa ni oko ni akoko naa. O beere lọwọ awọn oṣiṣẹ rẹ iru ẹniti Rutu i-se.
- Wọn ṣe alaye fun un ni ẹkunrẹrẹ, aanu Rutu si ṣee. O gba a tọwọ-tẹsẹ o si fun un ni ẹbun ati anfaani ti o pọ. O rọ awọn oṣiṣẹ rẹ lati maṣe ni Rutu lara.
- Gẹgẹ bi ẹniti o mọ oore, Rutu dupe pupọ lọwọ re, “O wolẹ, o si tẹ ara rẹ ba silẹ, o si wi fun un pe, Eeṣe ti mo ri oore-ọfẹ li oju rẹ, ti iwọ o fi kiyesi mi, bẹẹni alejo ni emi” (Rutu 2:10).
- Boasi sure fun Rutu ni ẹsẹ ekejila wipe; ki Oluwa ki o san an li ẹsan iṣẹ rẹ.
- Rutu fi gbogbo ara ṣiṣẹ ninu ọgba ni ọjọ naa gẹgẹbi iṣe rẹ. Eyi jọ Boasi loju o si fun Rutu ni ọka ti o pọ. Oun ati iya ọkọ rẹ jẹ ajẹ’yo ati ajẹ’ṣẹku.
- Inu iya ọkọ rẹ dun o si yan lati pese ibujoko rere fun un. Naomi kọ Rutu ni ohun ti yio ṣe lati le fẹ ibatan ọkọ rẹ. Rutu gba imọran lati lọ sun si ẹba ẹsẹ Boasi. Lẹhin igbesẹ ti o tọ, o di iyawo Boasi, o si bi OBEDI – Itumọ eyi ti i-ṣe “A bi ọmọkunrin kan fun Naomi”.
- Rutu gbe ọmọ naa fun iya ọkọ rẹ lati tọ. O fi tu u ninu. Obedi si bi Jesse, Jesse si bi Dafidi ninu iran ẹniti a ti bi Olugbala ar’aiye – Jesu Kristi.
- Ẹkọ ti a kọ lara igbe aiye Rutu: –
- Rutu jẹ obinrin rere. O duro ti iya ọkọ rẹ pẹlu iwa ododo ninu Ọlọrun, lẹhin iku ọkọ rẹ ati ninu ipọnju.
- O duro gẹgẹbi aya tootọ pẹlu ibaṣepọ ninu ifẹ ati igbagbọ ninu Ọlọrunl pẹlu ẹbi ọkọ rẹ.
- O jẹ olododo laisi ẹtan ninu iṣesi rẹ. Rutu gbagbọ ninu Olorun Alaaye. O fi ilu ati aṣa ‘rẹ sile lati tẹle iya ọkọ rẹ.
- Iwa rẹ ati iṣesi rẹ mu ki alafia ati ifọkanbalẹ jọba laarin oun ati ẹbi ọkọ rẹ.
ẹ. Rutu jẹ akikanju obinrin. O ṣe iṣẹ tọkan–tara ni oko Boasi lati toju iya ọkọ rẹ.
- Rutu jẹ iyawo olotitọ ati obinrin rere ti o duro dede, lẹhin iku ọkọ rẹ, bi o tilẹ jẹ wipe ko bimọ, o gbọnran si iya ọkọ rẹ lẹnu eyi si mu ki igbe aiye rẹ yipada si rere.
- Rutu fi ara balẹ titi Boasi fi ṣe ohun ti o tọ ninu ẹbi wọn lati maṣe mu itiju ba ara rẹ.
- Ọlọrun san ere iṣẹ rere rẹ fun un nipa fifun-un ni olu-ọmọ nipasẹ ẹniti Olugbala fi wa si aye.
- Mo rọ awa ọmọ Agbo Maria Mimọ ati gbogbo iyawo-ile lapapọ, lati kọ ẹkọ ninu igbe aiye Rutu ki ile wa ba le jẹ ile alayọ. Ọpọ ni awọn obirin ti ko le fi ara da, iya ati baba ọkọ wọn. Ti ẹbi ọkọ ko jẹ ohunkohun fun nwon. Li otitọ; ile ọkọ, ile ẹkọ ni, ṣugbọn, bi a ba fi ara b’alẹ, ti a si ni amum’ọra, ohun gbogbo yio tuba-tuṣẹ. Suru igba diẹ, a maa fun obinrin ni anfani pupọ lati jẹ ere ile ọkọ ni ẹkunrẹrẹ.