AGBARA AHỌN, LATI KỌ TABI BIWO

melissa-chabot-100925-unsplash_50

Ẹyin Ayanfẹ Ilẹ Miṣẹni ati ẹyin ti a k’ọju si ṣe l’oore, ti a si yan, ti o tun ni anfani, lati jẹ ẹlẹri si, igba ati fifi Ọba titun Rẹ si ori oye, gẹgẹbi aṣooju BABA ni aarin awọn eniyan Rẹ; maṣe gba ki igbera-ẹni-ga, oju kokoro, ilara, ibinu oun ikorira, jẹ atọkun aiye rẹ, gẹgẹbi ọmọ Ilẹ Miṣẹni.

Gẹgẹbi ẹlẹran ara, o di dandan ki akoko ibinu ati ede-aiye’de wa laarin awa ọmọ enia; ṣugbọn, ni akoko bi eyi; a ko gbọdọ sọ ọrọ buburu tabi ọrọ aidara ni akoko ibinu.
Nitori, ibinu ọkan yio lọ’le lẹhin igba diẹ, ṣugbọn, ki yio si anfani lati gba pada, ọrọ ti iwọ ti sọ s’ilẹ.
A ni lati maa lo ọgbọn pẹlu iṣọra fun awọn ọrọ ti yio ma ti ẹnu wa ja de.

Ahọn jẹ ohun elo fun aṣẹ.
Bi o tilẹ jẹ wipe ọpọ enian ni wọn nlo ahọn, diẹ ninu nwọn ni o mọ ipa ati wiwuwo rẹ.
Eeṣe ti awọn ẹranko ko lee sọrọ?
Awọn eweko ati oke nla pẹlu?
Bawo ni ọmọ enian ṣe wa ni anfani lati maa sọ ọrọ?
Idi ni wipe, a da ọmọ enian ni aworan Ẹlẹda ni ẹkunrẹrẹ, ni ọna ti awọn ohun iṣẹ ọwọ Rẹ gbogbo ti o ku ko ni anfani bayi.

Ti Ẹlẹda ba ti paṣẹ, o ti di ṣiṣe.
Eyi ni agabara ti enian ni, ṣugbọn ti oye rẹ ko ye ọpọ ninu wa. A si ma nro wipe, ti a ko ba ri ipa ọrọ ti a sọ ni kiakia, pe iru ọrọ bẹẹ, ko ja mọ nkankan ni.
Ere aini igbagbọ ni eyi. Gẹgẹbi ọjọgbọn ti o fẹ esi ni kia kia, mọ daju wipe, ti iwọ ba ti pe gbolohun ifẹ ọkan rẹ, lọgan ni imuṣẹ rẹ ti bẹrẹ.

Ọrọ ni itumọ. Bi iwo ba si ṣe tumọ ọrọ, bẹẹ ni agbara ọrọ bẹẹ yio ṣe dari iwọ ati ayika rẹ.
Ọrọ ti iwọ ba sọ pẹlu igbagbọ yio ri imuse pipe, bakanna ni eyi ti nṣe ọrọ awada. Ọrọ ẹfẹ, eyi paapa ni agbara aṣẹ tirẹ.
Aṣẹ ọrọ, lati inu wa ni eyi, oun yio si d’arapọ mọ agbara ti ode. Itumọ eyi ni wipe, ọrọ ti a bi fi igbagbọ pipe sọ, eyi yio wa iru ara rẹ kaakiri agbaiye, imuṣẹ ọrọ bẹẹ ni ẹkun rẹrẹ yio si ṣẹlẹ.

Ti ọrọ ba ti jẹ sisọ, ero ọkan rẹ ni eyi. Eyi ni ohun ti awọn Woli iṣaju sọ wipe; ‘‘ọrọ ẹnu rẹ, ki yio pada, lai ṣe iṣẹ, eyi ti iwọ ran an’’. Sibẹ, ọpọ a si sọrọ ti ko ni anfani kan pato.
Nitori naa, gbiyanju lati s’ọrọ pẹlu ero ọkan pipe ni igba gbogbo, bẹẹ ni, iwọ yio si ri agbara ti iwọ ni.

Ninu oyun abiyamọ, lẹhin oṣupa mẹsan ni ọmọ titun yio jẹ bibi si inu aiye. Oye fi ye wa wipe, ọmọ titun yi ti wa ni aaye ni gbogbo akoko yi, nitori wipe, ẹmi mbẹ ni gbogbo igba.
‘ẸMI’ ti wa, ki oyun to de.
Ọrọ, ẹmi ni.
Bayi ni ki iwọ ri ahọn rẹ, gẹgẹbi ohun elo ti o ngbin eso. Ero ọkan rẹ ni yio si sọ iru eso ti yio jẹ gbigbin. Idagba-soke eso bẹẹ pẹlu, yio rọ mọ ero ọkan rẹ, iṣesi ati ọrọ ẹnu rẹ.
Ti iwọ ba gbin eso rere, ti iwọ si bu omi rin, baa sọrọ ni gbogbo igba pe, ki o so eso rere, yio si ni ikore rere.

Ti iwọ ba gbin eso rere, ṣugbọn ti o ko b’ojuto, lotitọ yio hu jade, ṣugbọn, ikore rẹ ko le dabi.
Ti iwọ ba gbin eso buburu ti eyi si ṣe ako’ba fun ohun ọgbin rẹ ti o ku, ara rẹ ni iwọ yio da lẹbi.

Eyi ni ohun ti Angẹli Rafaẹli sọ nipa ahọn:
Lo ahọn rẹ fun iyin Rẹ, ati ohun gbogbo ti o wa fun gbigbe orukọ Mimọ Rẹ ga nikan.
Lo ahọn rẹ fun mimu ireti ati ayọ ba eti ti o gbọ ọ.
Lo ahọn rẹ fun mimu o sunmọ Ijoko Rẹ, yio si dara fun ọ.
Ahọn kii da ṣe iṣẹ. Ifihan ahọn rẹ ni ọrọ ti iwọ ba sọ. Bẹẹ ni, lati inu ero ọkan rẹ ni ọrọ ti iwọ sọ jade ti suyọ. Dajudaju, ọkan rẹ ni atọkun fun ahọn rẹ. Eyi ni yio si dari ọrọ ti iwọ ba sọ, ati bi iwọ yio ṣe sọ ọ pẹlu.
Nitori idi eyi, ṣe akoso ọkan rẹ ni daradara, ki o si mọ agbara ti mbẹ ninu ahọn rẹ.

Ọlọgbọn yio sọ wipe, ninu eko iṣiro; ohun meji pẹlu ohun meji, eyi yio di ohun mẹrin. Otitọ ni oun sọ.
Alaimọkan a si ṣe iṣiro wipe; idapọ ohun ọkan pẹlu ohun ọkan, yio di ohun mẹta. Ṣugbon ahọn tirẹ ko sọ otitọ, bẹẹ ni ko sọ bi o ṣe ri. Iparun ni eyi.
Otito a maa kọ ile, irọ a si maa bi i wo. Nitori idi eyi, gbiyanju ki otitọ maa fi ara han ọ, tobẹẹ, ti iwọ ba sọrọ, iwọ yio maa kọ ile ni, dipo bibi i wo.

Kini eyi tumọ si?
O tumo si wipe, Ahọn (ọrọ) ni agbara kikọ tabi bibajẹ, ṣugbọn orisun agbara bi eyi, ni ọkan (ero), iṣesi ati idawọle rẹ.

Lati gberu, ẹda ni lati ṣe aṣaro lori otitọ, fi agbara ninu otitọ han, ki oun si gbe igbe aiye otitọ. Ẹni ti o ba ṣe eyi, oun yio maa gberu si ninu aaye rẹ, ati ni ayika rẹ pẹlu. Nitori wipe, ti ẹda ba gbọ otitọ, eyi da bi eso rere ti o jẹ gbingbin si ọkan rẹ, eyi ti o si ni anfani lati so eso rere.

Ni idakeji ẹwẹ, ibajẹ yio jẹ ti ahọn ti o kun fun irọ pipa, ati aiṣe ododo. Eyi yio si mu idaamu ati irukerudo wa, eyi ti yio si ṣe okunfa iparun fun ẹda bẹẹ, ati awọn ti o yi ẹda bẹẹ ka.
Nitori idi bi eyi, ẹda ni lati ṣọra nipa ero ọkan, ati isọrọ ẹnu jade.
Beere lọwọ ara rẹ, njẹ ti iwọ ba sọ ero ọkan rẹ jade, njẹ iwọ nṣe ikọle (otitọ sisọ) ni, tabi, iwọ nṣe ibajẹ (titan irọ ka)?
O dara ki o pa ẹnu rẹ mọ ju wipe, ki o ṣe okunfa irukerudo ati ibajẹ lọ.
Ẹyin arami….
Ẹ ṣọ ero ọkan nyin;
Ẹ ṣọ ọrọ ẹnu nyin;
Ẹ ṣọ iṣesi nyin.

Ẹ ṣọra fun ipolongo idajọ irọ. Ọlọrun nikan ni O wa ni ipo Idajọ otitọ. Gba ẹda gbogbo bi won ṣe jẹ, ki o si yẹra fun idalẹbi nwọn lai fi idi ododo mulẹ. Eyi paapa jẹ ọna ibajẹ fun iwọ ati eti ti o gbọ ọrọ bẹẹ.

Tiraka lati gba ẹda gbogbo gẹgẹbi aworan Ẹlẹda. Kọ oju si iṣe ati idagbasoke tirẹ, eyi ni iṣẹ naa, ti a pin fun ọ.
Ti iwọ ba ni akoko to bẹẹ lati polongo idajọ fun arakunrin rẹ, yala ni didara tabi ni buburu, eyi fi han wipe, ohun ti ko ni anfani, ni iwọ nfi ngba ọkan rẹ ni’ṣe. Eyi si npe fun atunṣe.

Aworan ati iriri Ọlọrun, ki i ṣe ohun ti a nf’ojuri. Ṣugbọn eyi ni agbara lati dabi Ọlọrun.
Ọlọrun ko dabi iriri ọmọ enian, ti a nwo. Itumọ eyi ni wipe ninu ọmọ enian ni ohun gbogbo ti o duro fun Ọlọrun gbe wa.

Ọlọrun, A maa ronu,
Ọlọrun, A maa sọrọ,
Ọlọrun, A maa ṣiṣẹ.

Ti iwọ ba mọ eyi, ti o si nṣe imulo ero ọkan rẹ ni akoko, igbayi ni iwọ yio da bi Ọlọrun. Ṣugbọn, ọpọ ni o ti padanu iru ipo bi eyi, nitori ohun ti aiye.

Ohun ti Ọlọrun, ti aiyeraiye ni.
Iwọnyi si nji dide lati ipo oku.
Iwọnyi a si maa sọ di alaaye.

Ohun aiye yio di ibajẹ, iwulo nwon yio si ba aiye lọ.
Ahọn ni agbara pupo nitori ipo aṣẹ ti o wa. Ohun ti ahọn ba si sọ, eyi jade wa lati inu ero ọkan ẹda ni.
Idi ni eyi ti o fi jẹ wipe, agbara Ahọn le mu ilosiwaju wa, o si le ba nkan jẹ pẹlu.
Gba lati maa kọ ipilẹ rere ni igba gbogbo.

Leave a Reply