IJỌBA ỌLỌRUN – IHINRERE KRISTI SI ENIA GBOGBO

post2

1. Ẹkọ Bibeli fun ọrọ iṣiti oni ni a mu lati Ihinrere Luku 8:1-3, eyi ti o ka wipe:
“O si ṣe lẹhinna, ti o nlà gbogbo ilu ati iletò lọ, o nwasu, o nrò ìhin ayọ̀ ijọba Ọlọrun: awọn mejila si mbẹ lọdọ rẹ̀.
Ati awọn obinrin kan, ti a ti mu larada kuro lọwọ awọn ẹmi buburu, ati ninu ailera wọn, Maria ti a npè ni Magdalene, lara ẹniti ẹmi èṣu meje ti jade kuro,
Ati Joanna aya Kusa ti iṣe iriju Herodu, ati Susanna, ati awọn pipọ miran, ti nwọn nṣe iranṣẹ fun u ninu ohun ini wọn.”

2. Jesu ninu ihinrere rẹ lati polongo ijọba Ọlọrun gba awọn ọkunrin ati obirin laaye lati ni ipin ninu itanka ijọba Ọlọrun yi, laisi iyasọtọ, idalẹbi ati itanu awọn ti o ku diẹ kaito fun ati paapa awọn ti awa ọmọ enia ti gbagbọ wipe o ti sọnu.

3. KINI IJỌBA TITUN ỌLỌRUN YI GAN?
Jesu ninu ẹkọ rẹ nipa ijaya ati aniyan ọmọ enia ni Mat 6:33 sọ wipe:
“Ṣugbọn ẹ tète mã wá ijọba Ọlọrun na, ati ododo rẹ̀; gbogbo nkan wọnyi li a o si fi kún u fun nyin.”

4. Ijọba titun Ọlọrun ni koko ọrọ iyanju ti Jesu Kristi fi bọ gbogbo enia ni orilẹ ede aiye. Eyi ki iṣe ohun ti a nwa kiri, ṣugbọn ohun ti ngbe inu wa gẹgẹbi Ẹmi Ọlọrun fun gbogbo ẹniti o gba Jusu gbọ gẹgẹbi Ọmọ Ọlọrun ati Olugbala araiye.
Eyi si jẹ ohun ti awa ọmọ enia ti nlepa rẹ lati igba ati akoko Jesu Kristi, Oluwa wa titi di oni yi.

5. Luku 17:20-21: “Nigbati awọn Farisi bi i pe, nigbawo ni ijọba Ọlọrun yio de, o da wọn li ohùn pe, Ijọba Ọlọrun ki iwá pẹlu àmi:
Bẹ̃ni nwọn kì yio wipe, Kiyesi i nihin! tabi kiyesi i lọhun! sawõ, ijọba Ọlọrun mbẹ ninu nyin.”

6. Ni ifesi si awọn Farisi, Jesu Kristi fi ye gbogbo enia wipe ijọba Ọlọrun yi ngbe inu ọmọ enia gẹgẹbi ẹmi Ọlọrun. Bi a si ti ngba Jesu Kristi sinu aiye wa, ijọba yi yio ma gberu, fidimulẹ ati gbooro si i ni ọkan onigbagbọ.
Ilàkaka lati wọ̀ oju-ọ̀na tõro, ṣe pataki, nitori ọpọ enia ni yio wá ọ̀na ati wọ̀ ọ, ṣugbọn ti nwọn kì yio le wọle. Eyi pe fun igbiyanju lati tẹle ẹkọ ti Jesu Kristi kọ awa onigbagbọ.

7. Ni ode oni ọpọ ni ile ijọsin, ọpọ ni awọn ojiṣẹ Ọlọrun, ọpọ ni ikede ati iwasu ọrọ Ọlọrun, bẹẹ ni ọpọ ni i-ṣe adura ti o ngberu si i lati ọwọ awa onigbagbọ. Sibẹ ọpọ ọmọ enia ṣi wa ninu igbekun ẹṣẹ, bẹẹ ni iṣoro, ipọnju ati ijakulẹ ni igbesi aiye ọpọ onigbagbọ npeleke si i, laisi iyipada tabi idande. E ṣe?

8. Ohun ti o fa ipo ijakulẹ bayi ni aiye awa onigbagbọ ni wipe, a kọ lati kẹkọ ninu iriri wa ti atẹhinwa. Adamu ati aya rẹ Efa kọsẹ nipasẹ ayika wọn. Eṣu lo ohun ti o wa ni ayika wọn lati ba agbara ti Ẹlẹda da mọ wọn ninu jẹ. Iru ọna madaru bayi ni eṣu yi nfi gbọn ire ọpọ ọmọ enia ati ni pataki awa onigbagbọ danu titi di oni yi.

9. Awa onigbagbọ, ani awa ọmọ lẹhin Kristi ti ode oni fẹ ohun aiye yi ju ti ohun ẹmi lọ. Dipo ki a maa dagba soke ninu agbara ti ẹmi, ti nṣe ohun ti Ọlọrun fi ṣẹda ọmọ enia ni dida a ni iriri ati aworan ara Rẹ, ṣe ni awa ọmọ enia nle owo, ọla, ipo, ohun afẹ aiye, papa julọ ni ile ijọsin, ani ni ile Ọlọrun.

10. Idiriji ẹṣẹ, ironupiwada, ibẹru Ọlọrun, iye ainipẹkun, iwa mimọ, ifarada, ọrun apadi gbogbo iwọnyi ti di ohun igbagbe ninu ijọ Ọlọrun. Oluṣọ aguntan ti di iranṣẹ eṣu, ẹniti ohun aiye ati ifẹ ẹran ara ti bo loju. Ile Ọlọrun ti di ibi owo, ni bi ti ọrọ Ọlọrun ko ni ipa mọ. Ọpọ ile ijọsin ni a da silẹ lati ko ọrọ jọ, lati ọwọ awọn aiyederu alufa. Ọpọ ijọ ni ki iṣe ijọ Kristi, ti iṣe ijọ ọmọ enia lasan.

11. Mat 16:26 “Nitoripe ère kini fun enia, bi o jèrè gbogbo aiye, ti o si sọ ẹmí rẹ̀ nù? tabi kili enia iba fi ṣe paṣiparọ ẹmí rẹ̀?”
Ole ti ara ni ọpọ awa onigbagbọ nlo igba ati akoko wa lati ba jijakadi, nigbati a fi ẹmi ati ọkan wa silẹ lai daabobo fun eṣu lati gbakoso rẹ. Ọpọ ni aṣiro ati aṣiṣe awa ọmọ lẹhin Kristi, wipe pẹlu iku Jesu Kristi oore-ọfẹ wa lati jogun idariji ẹṣẹ, nigbati ko si ironupiwada. Irọ nla li eyi. Ko si ore-ọfẹ kan ti ko ni ipa ti ọmọ enia ni lati ko, ki o to le jogun eyi. Laisi ironupiwada ko lee si isọji ati isọdọtun fun ijọ Ọlọrun ati awọn olusin.

12. Ẹ jẹ ki a wa ni idide duro lati kọ orin ipinnu wa.
We have a gospel to proclaim
Good new for all throughout the earth
A gospel of our Father’s love
We sing His glory tell His worth.

We will not fear or be dismayed
By those who sneer or laugh at us
We have the confidence to say
That we shall forge ahead with faith.

Help us dear Lord, to trust in Thee
To do Thy will and never faint
Help us to hold our heads high up
And face the task on us bestowed. Amen.

13. Kọ wa Oluwa ki awa ki o le maa ka ọjọ aiye wa, ki a le maa fi ọkan wa si ipa ọgbọn. Amin.
Njẹ nisisiyi si Ọlọrun Baba, Ọmọ ati Ẹmi Mimọ ni a fi ọla, ogo, ipa, agbara, ijuba, ọpẹ, ibukun ati iyin fun, kai ati lai lai. Amin.

Leave a Reply