I-ṢE AWỌN AKỌNI AKIKANJU

waterfall

Ninu idije idibo fun ipo Arẹ orilẹ edẹ Amẹrika, eyiti o waiye ni ọdun diẹ sẹhin; ni a ti ri Akọni kan, ninu idije du ipo Arẹ ni orilẹ ede naa, lara awọn oludije fun ipo nla agbanla aiye yi.

Obirin bi ọkunrin yi, ti orukọ apejẹ rẹ njẹ Hilari Klintin, ni oludije ọkunrin akin-ẹlẹgbẹ rẹ ṣe apejuwe rẹ bayi gẹgẹbi akikanju ẹniti o ni igboya, ipinnu, aṣeyọri ati aṣeyege: laisi ibẹru tabi ifoya kan ti o tako ipinnu rẹ wipe – oun yio gbe igba oroke dandan lati di Arẹ orilẹ ede Amẹrika.

Ninu ọrọ tirẹ, Akọni Akikanju Olujide ati arabinrin yi – Hilari Klintin fi ẹnu ara rẹ sọ bayi “Emi funra tikalara mi mọ wipe, mo ti ṣetan, mo si ti pinnu lati jẹ obinrin akọkọ ti yio di Arẹ orilẹ ede Amẹrika lai wo ariwo ọjọ ati lai nani irohin ibajẹ awọn akọrohin ati akojọpọ awọn irohin iwọsi bẹẹ lori erọ aiyelujara, eyiti ki yio tu irun kan lara mi lori ipinnu ọkan mi lati gun ori aleefa gẹgẹbi Arẹ ati aṣiwaju orilẹ ede Amẹrika.”

Ẹnyin ara mi ninu Oluwa, njẹ mo bere lọwọ nyin, kini yio jẹ ipinnu emi ati iwọ nigbati ipenija ba de lori iṣẹ iriju eyiti Oluwa fi ran wa si iran enia? Ẹ jẹ ka ronu!

Eyi mumi ranri itan igbesi aiye iranṣẹbinrin kan ninu Iwe Mimọ ti a mọ orukọ apejẹ rẹ si Debora (Iwe Onidajọ, ori kẹrin ati ẹkarun). Itan igbesi aiye ati iṣẹ iriju arabinrin yi, ni mo woye wipe, o yẹ ki o jẹ ipenija nla fun iwọ ati emi gẹgẹbi obiirin lawujọ awọn ọkunrin ni saa igbe aiye ti akoko wa yi.

Akọsilẹ Akọni Akin-Obinrin yi fi ye wa wipe, ṣiṣe ifẹ Ẹlẹda ati jijẹ ohun elo iyebiye lọwọ Ọlọrun ko pin si ọdọ awọn ọkunrin nikan. Ọlọrun ninu eto mimọ Rẹ A maa lo awọn obinrin gẹgẹbi ohun elo iyebiye lati maa ṣe ifẹ Rẹ ati lati mu ipinnu ati aṣẹ Rẹ ṣẹ fun awọn ayanfẹ ati enia ini Rẹ.

Gẹgẹbi Debora ti jẹ ohun elo rere lọwọ Ọlọrun lati fi igboya ati ọkan-akin fun awọn ọmọkunrin Isirẹli pẹlu asọtẹlẹ iṣẹgun ti Ọlọrun ti pese silẹ fun wọn, bẹẹ gẹgẹ ni iwọ ati emi bi obinrin, jẹ ohun-elo iyebiye lọwọ Ọlọrun, bi a ba ti ṣetan, ti a si ti pinnu lati jọwọ ara wa silẹ fun ilo Rẹ.

Debora, Akọni Akin-Obirin ninu Iwe Mimọ jọwọ ara rẹ fun ilo Ọlọrun. Oun Ọlọrun si fi Sisẹra – ọta Isirẹli lee lọwọ ki iṣẹgun aṣẹtan lee jẹ ti awọn enia Rẹ.

Ẹnyin ara ninu Oluwa, ipenija nla ni itan yi jẹ fun gbogbo obinrin ọmọ lẹhin Kristi, gẹgẹbi oluranlọwọ Ade-Ori wa ni igbe aiye wa yi.
Ki a ma ṣe ri ẹniti yio dagunla tabi ka’wọrọ laiṣe ojuṣe rẹ ninu ọgba ajara Rẹ yi.
Agbara mbẹ fun awa obinrin yalla lati tunṣe tabi ṣe idakeji rẹ.

Mo bere, irufẹ obinrin wo ni iwọ ati emi ninu ijọ Ọlọrun ati lọdẹdẹ ọkọ wa?

Hilari Klintin gẹgẹbi Debora ninu Iwe Mimọ jẹ apẹrẹ rere awọn Akọni, Akikanju Akin-Obinrin ti ko gbadọ ninu aṣa na wipe, iyara-ibusun ati ẹhinkule ni ile-idana ni ipo awọn obinrin wa. Ṣugbọn yatọ si ero bẹẹ, awọn arabirin wọnyi ji giri si lilo ẹbun ati ore-ọfẹ ti Ọlọrun fi fun wọn – eyiti i-ṣe ẹmi akin, igboya, ọgbọn, imọ, oye ati ti akọni-loju-ija fun iṣẹ Rẹ lai wipe ohun kan wa ti wọn ko le dawọle gẹgẹbi awọn ọkunrin Akin-ẹlẹgbẹ wọn. Igbagbọ awọn Akọni Akin-Obinrin wọnyi ni wipe, ohun ti ọkunrin le ṣe obinrin le ṣe daradara ju bẹẹ lọ.

Ohun kan ni, Obinrin bẹẹ ni lati ni igbagbọ ati idaniloju ninu ara rẹ, laisi irẹwẹsi, iyemeji, ibẹru ati ifoya, pẹlu imọ wipe ohungbogbo ni ṣiṣẹ nipa agbara ati ore-ọfẹ Ọlọrun. (Gẹnẹsisi 18:14)

Ẹyin ara mi ninu Oluwa, agbara aṣe ati ore-ọfẹ nlanla ni o wa fun emi ati iwọ gẹgẹbi obinrin – ni ọgbọn, imọ ati ete lati tunṣe tabi ṣe idakeji rẹ. Ati ni pataki lati mu awọn Ade-ori wa ṣe eyiti ọkan wa nfẹ fun ogo Ọlọrun.

Mo beere: bawo ni iwọ ati emi ṣe nlo ore-ọfe yi gẹgẹbi ọrun ti o gbe Ade-ori wa ro ti o si ndari Ade-ori bẹẹ si ibiti ọ yẹ.

Gẹgẹbi obinrin ti Ẹlẹda da lati iha awọn arakunrin wa, ẹ jeki a beere lọwọ Ọlọrun; agbara ati ore-ọfe lati maa ṣe ife RẸ: eyiti yio mu wa jẹ oluranlowo tootọ fun awọn Ade-ori wa to bẹẹ gẹ ti ẹbi wa yio maa rin ni ọna imọlẹ, iye, otitọ ati ododo ọrọ RẸ lati maa jẹ apẹrẹ ati awokọṣe rere lawujọ iran ẹniyan.

Larin awọn Akikanju Akoni Akin-Obinrin mejeji wọnyi ni a ti le ri awọn ẹkọ pataki wọnyi kọ ni aridaju.
– Akọni loju ija ni awọn aṣayan ẹmi na.
– Wọn ni igbagbọ ninu ara wọn.
– Wọn jẹ amoye ati Ọjọgbon ninu ero ati iṣe wọn ninu ile, nibi isẹ ati ni ile ijọsin.
– Wọn jọwọ ara wọn sile fun iṣẹ Ọlọrun ati iwulo fun iran eniyan.
– Wọn gbẹkẹle Ọlọrun wọn yatọ si ẹran ara wọn.

Ẹyin ara mi ninu Oluwa, akoko ti to lati fi awọn ohun idiwọ bi arankan, ati tẹmbẹlẹkun ṣilẹ ki a si jẹ ipe naa lotitọ ati lododo. Ọlọrun to pe wa: Oun lo yan wa. Oun na lo ṣe wa logo pẹlu agbara imọlẹ RẸ fun idande ati irapada ẹda eniyan gbọgbo lode aiye. Ninu iṣẹ iriju wa yi ni awa ni ohun amuyangan gẹgẹbi ayanfe, ọrẹ Ọlọrun, ọmọlọju ati ẹni mimọ RẸ ti isalẹ.

Adura mi ni wipe: ki Ọlọrun gba iṣakoso aiye wa: ki O si fi agbara Ẹmi mimọ ati ore-ọfẹ RẸ fun wa lati le ṣe ojuṣe wa de oju ami ni kikun. Amin.

Ogo ni fun Ọlọrun Baba, Ọmọ ati Ẹmi Mimọ lai ati lailai. Amin.

Leave a Reply